Tọkọ-taya yii ji ara wọn gbe pamọ, wọn fẹẹ fi gbowo lọwọ mọlẹbi wọn

Faith Adebọla, Eko

Bii ẹni n ṣere ori itage lọrọ naa jọ, ṣugbọn ki i ṣe ere ori itage rara, wọn ko si ya fiimu agbelewo, iṣẹlẹ to waye gidi ni, iyẹn bi tọkọ-taya kan tawọn ọlọpaa ko fẹẹ darukọ wọn ṣe dero ahamọ, latari pe wọn tilẹkun mọri, wọn fi ara wọn pamọ, n ni wọn ba fi atẹjiṣẹ ṣọwọ sawọn mọlẹbi wọn gbogbo pe awọn ajinigbe kan ti ji awọn gbe sa lọ, miliọnu marun-un Naira (N5m)si ni wọn fẹẹ gba, wọn ni kawọn mọlẹbi awọn tete ba awọn wa owo naa ni kiakia, ki wọn ma jẹ kawọn ku sibi tawọn wa yii, tori ahamọ awọn ajinigbe-gbowo kan lawọn wa lọwọlọwọ, bẹẹ wọn o kuro labẹ orule ile wọn o.

SP Benjamin Hundeyin, ti i ṣe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, lo sọrọ yii di mimọ fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin yii.

O ni ọkan ninu awọn mọlẹbi baale ile to purọ ijinigbe mọra ẹ yii lo sare janna-janna wa si teṣan ọlọọpa, lẹka ileeṣẹ wọn to wa ni Badagry, pe kawọn ọlọpaa gba awọn, awọn ajinigbe-gbowo kan ti ji eeyan awọn lọ o, bẹẹ lo si fi atẹjiṣẹ ori foonu ẹ han awọn ọlọpaa gẹgẹ bii ẹri. O ni iṣẹ-ọwọ ni baale ti wọn ji gbe ọhun n ṣe, iyawo ẹ ti wọn jọ wa lakata awọn ajinigbe n ṣiṣẹ awọn to maa n wọ ara, ti wọn n to ara ati egungun, eyi ti wọn n pe ni masaaji (massage) lede oyinbo, agbegbe Badagry si ni wọn n gbe.

Oju-ẹsẹ ni ikọ ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa ti tẹsẹ bọ ọrọ naa, wọn si bẹrẹ iwadii ijinlẹ lati mọ ibi ti eefin ina buruku naa ti ru wa, amọ iyalẹnu lo jẹ nigba ti wọn fi imọ ẹrọ tọpa atẹjiṣẹ naa, ti wọn si lọ sile tawọn tọkọ-taya yii n gbe ni Badagry, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin yii, wọn ba ilẹkun ile ni titi pa loootọ, bii pe ko sẹnikan ninu ile ọhun. Amọ nigba to ya, wọn fura pe eeyan wa ninu ile naa, wọn si ṣilẹkun ile ọhun, ni wọn ba ba iyaale ile ti wọn ni wọn ji gbe atawọn ọmọ wọn mẹta ninu ile, wọn o si lakata ajinigbe kan, baale wọn nikan ni ko si nile.

Hundeyin ni awọn ọlọpaa fẹẹ mu obinrin naa lọ si teṣan, amọ o bẹ wọn pe ki wọn ma jẹ koun fawọn ọmọ naa silẹ lati da nikan sun ile naa mọju, eyi lo jẹ kawọn agbofinro fi i silẹ di ọjọ keji, ti wọn ni ko yọju sawọn ni teṣan awọn.

Obinrin naa mu adehun ṣẹ lọjọ keji loootọ, iyẹn Wẹsidee, o yọju si teṣan Badagry, wọn si mu un sọ sahaamọ. Nigba to di Tọsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, awọn ọlọpaa dọdẹ ọkọ rẹ, wọn si mu oun naa.

Ni teṣan ni baale ile yii ti jẹwọ fawọn ọlọpaa pe loootọ loun purọ pe awọn ajinigbe ji oun atiyawo oun gbe, o ni owo loun n wa, tori awọn ti ta ile awọn tawọn n gbe, awọn si fẹẹ ra ile naa pada lọwọ ẹni tawọn ta a fun, miliọnu mẹta Naira lawọn nilo lati fi ra ile naa pada, igba toun wa ọgbọn toun maa da toun ko ri loun ṣe purọ buruku naa. O loun loun di ọrọ naa lawo pẹlu iyawo oun, awọn fẹẹ fi gbowo lọwọ awọn ana awọn ni, paapaa awọn eeyan iyawo oun, tori oun mọ pe ti wọn ba gbọ pe ọmọ wọn wa ninu igbekun, owo aa jade.

O fi kun un pe bawọn ọlọpaa ṣe n wo oun yii, oun lawọn ti wọn ri jajẹ daadaa ninu famili oun o, tawọn ẹgbọn ati aburo oun kan ninu wọn si wa niluu oyinbo pẹlu, amọ wọn lahun ju ijapa lọ, wọn hawọ gidi ni, wọn ko fi owo wọn ba oun ṣere ri, eyi si wa lara ohun to ṣokunfa nnkan toun ṣe yii.

Wọn beere lọwọ iyawo naa, o ni bọrọ ṣe jẹ gẹlẹ lọkọ oun sọ yẹn, owo lawọn n wa, miliọnu mẹta gan-an lawọn nilo, awọn kan tun fi miliọnu meji kun un ninu atẹjiṣẹ yẹn ni.

Ṣa, Hundeyin ti ni awọn ṣi n ba iṣẹ iwadii niṣo, lẹyin iwadii lo lawọn maa jẹ kawọn tọkọ-taya aturọta bii elubọ yii foju bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply