Haa, o ma ṣe o, eeyan meje ku lojiji!

Aderounmu Kazeem

O kere tan, eeyan meje ni wọn padanu ẹmi wọn lowurọ kutu oni nigba ti bireeki ọkọ tirela kan ja lojiji, to si pa wọn lojuẹsẹ.

ALAROYE gbọ pe adugbo kan ti wọn n pe ni Bell junction, lagbegbe Bell Yunifasiti, lojuna Idiroko nipinlẹ Ogun niṣẹlẹ buruku ọhun ti waye.

Wọn ni lojiji ti bireeki mọto ọhun ja lo ya bara lọọ kọ lu awọn onikẹkẹ Marwa atawọn ọlọkada, to si pa eeyan meje lẹsẹkẹsẹ, tọpọ eeyan si farapa pẹlu.

Yato si eyi, pupọ ninu awọn kẹkẹ marwa ati ọkada to wa nibi ti mọto yii ya si lo bajẹ patapata.

Ọkunrin kan, Gbenga Oṣinaike, tiṣẹlẹ ọhun ṣoju ẹ sọ pe baba agbalagba kan lo kọkọ ku ninu iṣẹlẹ ọhun nigba ti awọn mẹfa yooku ku ki wọn too le ṣeranlọwọ kankan fun wọn.

Bi iṣẹlẹ ọhun ti waye lawọn eeyan agbagbe naa ti fi ibinu ki dẹrẹba to wa mọto ọhun mọlẹ, ti wọn si lu u lalubami. Awọn eeyan kan ni wọn sare gba a silẹ lọwọ wọn, ṣugbọn nibẹ naa ni wọn ti dana sun mọto ẹ, to fi da ẹmi awọn ẹni-ẹlẹni legbodo.

Ọga agba fun ẹṣọ ojupopo nipinlẹ Ogun, Ahmed Umar, sọ pe loootọ ni eeyan meji ku, ṣugbọn o ṣeni laanu wi pe ikọ awọn ko le ṣe ohunkohun nigba ti awọn debẹ, nitori bi awọn eeyan ṣe fabinu yọ, ti wọn si sọ iṣẹlẹ ọhun di wahala rẹpẹtẹ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

2023: Ẹgbẹ TOTT rọ Tinubu atawọn oludije yooku lati panu pọ gbe Ọṣinbajo kalẹ

Ọrẹoluwa Adedeji Ẹgbẹ kan, The Ọsinbajo Think Tank (TOTT), ti parọwa si aṣaaju ẹgbẹ oṣelu …

Leave a Reply

//zikroarg.com/4/4998019
%d bloggers like this: