Hijaabu: Ajọ CAN binu sijọba Kwara, wọn ni gbọgbọ ọna lawọn yoo fi ta ko wiwọ hijaabu lawọn ileewe awọn

Stephen Ajagbe, Ilorin

Lẹyin tijọba ipinlẹ Kwara paṣẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, pe awọn akẹkọọ-binrin to jẹ Musulumi laṣẹ lati maa wọ ibori ta a mọ si hijaabu lawọn ileewe to jẹ ti ẹlẹsin Kristẹni, ṣugbọn tijọba n mojuto, ajọ CAN nipinlẹ Kwara ti ta ko aṣẹ naa, wọn ni ko si aaye fun wiwọ ibori lawọn ileewe awọn.

Nibi ipade kan pẹlu awọn oniroyin niluu Ilọrin, lọjọ Ẹti, Furaidee, lẹyin bii wakati mejila tijọba gbe aṣẹ naa sita, ajọ ọmọlẹyin Kristi naa ni ohun tawọn n beere fun ni ki ijọba da awọn ileewe awọn pada fun awọn.

Agbarijọpọ awọn ọga agba ileewe Kristẹni lo peju sibi ipade awọn oniroyin ti CAN ṣe. Bakan naa lawọn adari ajọ naa wa nikalẹ.

Akọwe ajọ CAN nipinlẹ Kwara, Ẹni-Ọwọ Reuben Ibitoye, ati ọga agba to n mojuto ọrọ ile-ẹjọ ati ibaraalu sọrọ (Legal and Publicity), Alufa Ṣhina Ibiyẹmi, pẹlu awọn mi-in lo buwọ lu ohun ti wọn fẹnu ko naa.

Ẹni-Ọwọ Victor Adebayọ to gbẹnu sọ fun ajọ naa ni nibẹrẹ, nigba tawọn gba ile-ẹjọ lọ, ẹjọ tawọn pe ijọba ni ki wọn da awọn ileewe awọn pada, awọn ko pẹjọ lori hijaabu, iyalẹnu lo pada jẹ fawọn bi ọrọ hijaabu ṣe jẹ yọ.

Wọn ni gbogbo ọna lawọn yoo fi ta ko lilo hijaabu, awọn yoo ja fun ohun to jẹ tawọn.

Ajọ ọhun ni lọna ati gba alaafia laaye, ki awọn akẹkọọ to jẹ Kristẹni nikan maa lọ sawọn ileewe naa. Wọn ta ko pipe awọn ileewe awọn ni ileewe ijọba.

 

 

Leave a Reply