Ibadan lawọn Fulani ti jí Emmanuel gbe, ilu lsẹyin ni wọn lọọ ja a si lẹ́yìn ti wọn gbowo nla

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Leyin ọjọ mẹrin tó ti wa nígbèkùn àwọn ẹni ibi, ọmọ àgbẹ̀ tí wọn ji gbe n’Ibadan, Ayọdeji Emmanuel Ọdẹtunde, ti kuro nígbèkùn àwọn ajinigbe.

Ni nnkan bíi aago meje kọja iṣẹju mẹ́ẹ̀ẹ́dógún alẹ Ọjọbọ, Tọ́sìdeè, ọjọ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù kejì, ọdun 2021 yii, lawọn ẹbi ẹ̀ rí í nibi ti awọn ajinigbe já a jù sí lẹyin ti wọn gbowo lọwọ awọn ẹbi rẹ tan.

Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bíi aago meji ọsan ọjọ Ajé, Mọnde, ọjọ kejilelogun oṣù kejì, ọdun 2021 yii, láwọn igiripa mẹrin kan ya lu Emmanuel atawọn oṣiṣẹ baba ẹ nibi ti wọn ti n ṣiṣẹ lọwọ ninu oko wọn tó wà lagbegbe Òkè-Ọ̀dàn, Ọlọ́mọ, lagbegbe Apẹtẹ, n’Ibadan, ti wọn si ji ọmọkùnrin ẹni ọdún mẹrinlelogun to jẹ akẹkọọ imọ Sosiọ́lọ́jì ni Fasiti Ibadan (UI) na gbé.

Ọjọ kẹta ti í ṣe Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, láwọn ajinigbe ti wọn pe ni Fúlàní yii pe Ọgbẹni Ọdẹtunde ti í ṣe baba ọmọ naa pe awọn lawọn gbe e lọmọ, ati pe mílíọ̀nù lọna ọgọrun-un naira (100m) lawọn máa gbà lọwọ ẹ ki awọn tóo lè fi ọmọkùnrin naa silẹ. Wọn ní bo ba fi le fi asiko awọn ṣofo ti ko tete wa owo naa, pipa lawọn yoo pa a lọmọ sinu igbekun awọn ninu aginjù igbo.

Awọn ẹbi Ọdẹtunde kò lágbára owo ọhun, ṣugbọn lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ, a gbọ pe awọn ajinigbe gba miliọnu meji Naira ti wọn ri ṣà jọ lọwọ wọn.

Kayeefi ibi ọrọ yii waa ni pe dipo ilu Ibadan ti wọn ti gbe Emmanuel, ibi kan niluu Isẹyin ni wọn já a jù sí ti awọn ẹbi ẹ ti lọọ gbe e.

Leave a Reply