Hijrah: Ijọba ipinlẹ Ọyọ kede ọjọ Iṣẹgun fun isinmi lẹnu iṣẹ

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti kede ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹwaa, oṣu yii, gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ lati ṣami ayẹyẹ ọdun tuntun awọn Musulumi ti wọn n pe ni Hijrah 1443.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe ijọba ipinlẹ naa, Abilekọ Ọlabamiwo Adeọṣun fi sita lo ti ṣalaye pe Gomina Makinde rọ awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ lapapọ lati lo asiko naa ki wọn fi gbadura fun alaafia, iṣọkan ati imuduro ipinlẹ Ọyọ ati Naijiria lapapọ.

O yẹ ki ayẹwo ọpọlọ wa fun ẹnikẹni to ba fẹẹ darapọ mọ iṣẹ agbofinro lorileede yii – Ọladimeji

Leave a Reply