Iṣẹ Ọlọrun pọ o, were yii bi ibeji lai sẹni to gbebi fun un

Niṣe lawọn eeyan n gbe Ọlọrun ga lati ara obinrin yii, alarun ọpọlọ ni. Ọkunrin kan to maa n ba awọn eeyan re eekanna ni wọn lo fipa ba a sun lọdun to kọja, oyun ọhun lo si fi bi ibeji, ọkunrin meji lanti-lanti ti wọn rẹwa daadaa yii, iyẹn ni ọgbọnjọ, oṣu kẹjọ, ọdun 2021.

Orilẹ-ede Ghana ni were yii wa, nibi kan ti wọn n pe ni Obuasi, Ashanti. Ohun to ṣẹlẹ si i lo sọ ọ di ẹni to n rin kiri pẹlu akisa, arẹwa obinrin kan ni wọn pe e ko too yi lori.

Afi bi wọn ṣe ni ọkunrin kan to maa n ba awọn eeyan re eekanna wọn, ti wọn yoo sanwo fun un, fipa mu un mọlẹ lọdun to kọja yii.

Wọn ni ibalopọ to waye laarin wọn naa lo di oyun, nitori lẹyin rẹ lawọn eeyan ri i pe were naa ti fẹraku, titi to fi di pe inu rẹ bẹrẹ si i tobi gan-an.

Oyun ọhun lo fi bi awọn ọmọ to rẹwa gidi yii, ti wọn mọ lawọ, ti wọn si pupa daadaa bi wọn ṣe ri rubutu. Awọn eeyan to wa nitosi lo ṣugbaa ẹ bo ṣe n rọbi, wọn si ti ara rẹ gboṣuba fun iṣẹ Eledumare.

Ireti wa pe were naa pẹlu awọn ọmọ rẹ yoo ri aanu gba, ti aburu ko fi ni i ṣe awọn ẹjẹ ọrun yii, ti iya wọn naa yoo si pada ni ilera pipe.

 

Leave a Reply