Monisọla Saka
Peter Obi, ti i ṣe oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party, sọ pe oun ti beere idi tawọn ẹgbẹ oṣelu alatako ti wọn wa nijọba lọwọ bayii, All Progressives Congress (APC), ko ṣe fa Ọṣinbajo kalẹ gẹgẹ bii oludije dupo aarẹ fun eto idibo ọdun 2023 to ṣẹṣẹ pari yii. O ni ka ni ni nnkan bii ogun ọdun sẹyin ni Tinubu jẹ aarẹ ni, awọn eeyan ko ba mọ ijọba naa yatọ, nitori yoo ṣe e daadaa.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Obi sọrọ yii nibi ayẹyẹ apejọpọ ọjọ ibi ọdun kẹtalelọgọta ọkunrin oniṣowo, ati gbajumọ atẹweta oniroyin nni, Dele Momodu, ti wọn ṣe niluu London.
Ninu fidio kan ti ọmọ ọlọjọọbi gbe sori ikanni ayelujara Instagram rẹ ni Obi ti ni ojukoroju bayii loun beere lọwọ ẹgbẹ to wa nipo lori idi ti wọn ko ṣe fa Igbakeji Aarẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, kalẹ gẹgẹ bii oludije funpo aarẹ ọdun 2023.
Bẹẹ lo tun sọ fawọn ero to wa nibẹ pe ẹni ti APC fa kalẹ yii ko ba jẹ ọmọ oye gidi, ti gbogbo araalu yoo si mọ asiko rẹ si daadaa, to ba jẹ pe bii ogun ọdun sẹyin lo du ipo naa, to si wọle, o ni nitori eeyan to le fi gbogbo agbara ṣiṣẹ takuntakun ni ilẹ Naijiria nilo lọwọ yii.
O ni, “O wu mi ki Naijiria goke agba, ko di ilu amuyangan, mi o si fi eleyii bo nigba kankan, ati lọjọkọjọ. Koda, mo beere lọwọ awọn ẹgbẹ oṣelu APC, mo ni ki lo de tẹ o fa Ọṣinbajo kalẹ fun ipo aarẹ yin? Ki ohun gbogbo le rọgbọ fun gbogbo wa, o yẹ ka pese aaye to daa fawọn eeyan, ka le ri eeyan ti yoo ṣiṣẹ forilẹ-ede, lẹni to jẹ eeyan gidi ati ẹni to lalaafia daadaa “.
Obi ni ipo aarẹ toun du lasiko ibo to kọja yii ki i ṣe tori nnkan mi-in, bi ko ṣe lati le mu ki orilẹ-ede Naijiria daa ju bayii lọ.
Tẹ o ba gbagbe, Aṣiwaju Bọla Tinubu lo gbegba oroke ninu ibo abẹle ẹgbẹ APC to waye loṣu Kẹfa, ọdun to kọja, nibi ti Ọṣinbajo atawọn mi-in ninu ẹgbẹ wọn ti jọ figagbaga.