Nitori ti wọn ko fẹ ko lọ sile, awọn ọlọpaa tun sare gbe Ṣeun Kuti pada lọ si kootu

Monisọla Saka

L’Ọjọbọ Tọsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, lawọn ọlọpaa tun gbe Ṣeun Kuti, ọkunrin olorin ti wọn fi si ahamọ nitori agbofinro kan to fọ leti pada lọ si kootu Majisireeti to wa lagbegbe Yaba, nipinlẹ Eko, lati le gbawe aṣẹ lati le da a duro si atimọle fọjọ mẹrin mi-in. Eyi ni pe itimọle ni yoo ti lo opin ọsẹ yii.

Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karundinlogun, oṣu Karun-un, ni wọn kọkọ gbe Kuti lọ siwaju adajọ nitori agbofinro ti wọn lo gba leti lasiko ti tọhun wa lẹnu iṣẹ, ninu aṣọ ọlọpaa. Lọjọ yii kan naa ni adajọ fun awọn ọlọpaa laaye lati ti i mọle fun wakati mejidinlaaadọta, ti i ṣe ọjọ meji, ki wọn le raaye ṣewadii wọn daadaa. Amọ to ni ki wọn yọnda ẹ lẹyin ọjọ meji ọhun.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu yii, lo yẹ ki ọkunrin naa dari pada sile ẹ, ṣugbọn ti ko ribi lọ, nitori idaduro latọdọ adajọ, ati akọwe kootu Majisireeti naa.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Sahara reporters ṣe sọ, wọn ni adajọ ati akọwe kootu ti yoo buwọ lu iwe beeli Ṣeun ko tete de sẹnu iṣẹ. Lai si jẹ pe wọn fọrọ to agbẹjọro ọkunrin naa leti, niṣe lawọn ọlọpaa tun wọ ọ lọ sile-ẹjọ lọjọ Tọsidee, lati le bẹ kootu pe ki wọn fawọn laṣẹ lati da a duro fọjọ mẹrin mi-in si i.

Ẹni kan to ba akọroyin Sahara reporters sọrọ ṣalaye pe, “Lai ro tẹlẹ lawọn ọlọpaa sare gbe Kuti pada lọ si kootu lati gbaaye ọjọ mẹrin mi-in, lati le ṣe iwadii wọn bo ṣe tọ.

Dajudaju, wọn ṣe eleyii, lati bẹgi dina irinajo afẹ to fẹẹ lọ lati fi orin da wọn laraya niluu oyinbo, eyi ti yoo bẹrẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu yii.

‘‘Bo tilẹ jẹ pe adajọ naa ti paṣẹ pe ki wọn fi Ṣeun silẹ lẹyin ọjọ meji to ba lo latimọle, ki wọn si yọwọ yọsẹ ninu pe wọn n pe e lẹjọ, oun tawọn ọlọpaa sọ ni pe agbofinro ti Kuti fọ leti ko i ti i laju, ẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun ni wọn si sọ pe o wa nibi to ti n gba itọju nileewosan ti wọn ko darukọ rẹ’’.

Ṣa, Kuti to yẹ ko gba ominira l’Ọjọbọ, Tọsidee, ṣi wa lahaamọ awọn agbofinro titi ti adajọ yoo fi paṣẹ ọjọ ti wọn maa fi i silẹ.

Leave a Reply