Ibẹru Ọlọrun la fi maa ṣejọba tẹ ẹ ba fibo yin gbe wa wọle-Funkẹ Akindele

Monisọla Saka

Arẹwa oṣerebinrin onitiata ilẹ wa, to tun jẹ oloṣelu pataki to n dije funpo igbakeji gomina ipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Funkẹ Akindele, ti ṣeleri pe ẹgbẹ awọn yoo mu adinku ba iṣẹ ati oṣi to n ba awọn eeyan wọya ija, bẹẹ lawọn yoo sọ Ikorodu, nipinlẹ Eko, di agbegbe to jẹ oju ni gbese, ibi tawọn onileeṣẹ nla nla nilẹ yii ati loke okun yoo maa sa wa lati waa da okoowo wọn silẹ si, ti wọn ba le fibo gbe awọn wọle lasiko idibo to n bọ yii.

Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni obinrin to bi ibeji naa ti sọrọ yii nibi eto isin idupẹ to ṣe nileejọsin Celestial Church of Christ, ẹka ti Ibukun-Olu, olu ijọ wọn to wa ni Aleke, niluu Ikorodu, nipinlẹ Eko, lati fẹmi imoore han si Ọlọrun gẹgẹ bo ṣe gbe e de ipo pataki yii nidii oṣelu.

Funkẹ to ni Ọlọrun nikan lo maa n ba ẹda gbọ bukaata, to si maa n tan ọpọlọpọ iṣoro ẹda sọ pe, tawọn ba le depo gomina, oun ati oludije dupo gomina lẹgbẹ awọn, Abdulazeez Adediran, tawọn eeyan mọ si Jandor, yoo fi ibẹru Ọlọrun ṣejọba lori awọn araalu, lati mu adinku ba iya, iṣẹ ati oṣi to n ba awọn eeyan finra.

Bakan naa lo rọ awọn eeyan lati nigbagbọ ninu Ọlọrun, ki wọn si ṣe ohun to tọ lọjọ idibo. O tun fi kun un pe ẹri ati iṣẹ ọwọ Ọlọrun loun toun duro siwaju wọn yii, nitori ẹsẹ oun ṣi duro ṣinṣin nilẹ, pẹlu boun ṣe ti ro o pin lori gbogbo awọn nnkan toun ti la kọja nile aye.

O ni, “Lonii yii, inu mi dun gidi gan-an, mo si fẹẹ dupẹ lọwọ Ọlọrun lori gbogbo awọn nnkan ti mo ti gbe ṣe laye.

Mi o wa sibi lonii lati waa polongo ibo, bi ko ṣe lati dupẹ fun Ọlọrun, ki n si tun yin In pẹlu ẹyin ẹbi mi ninu ijọ mimọ CCC. Ẹ kan ṣaa maa ba mi dupẹ, kẹ ẹ si gbadura fun mi lati ma ṣe rogun adanwo ati adojukọ ti yoo lagbara ju mi lọ”.

Ọkan ninu awọn oluṣọ aguntan ijọ naa, Ẹfanjẹliisi Paul Adelaja, to ba a dupẹ lọwọ Ọlọrun gboṣuba kare fun igbakeji oludije dupo gomina lẹgbẹ PDP yii, fun iṣẹ takuntakun to ti ṣe ati bi Ọlọrun ṣe n lo o lati pa awọn eeyan lẹrin-in ayọ. Adelaja waa gba a laduura fun Funkẹ Akindele pe gbogbo adawọle rẹ pata ni yoo maa yọri si rere.

Lẹyin isin idupẹ yii ni Funkẹ tun lọ si ijọba ibilẹ Imọta (Imọta LCDA), niluu Ikorodu, nibi tawọn eeyan ti ki i kaabọ tilu tifọn.

Lasiko to n ba awọn eeyan sọrọ, Funkẹ ṣeleri pe awọn yoo ṣe atunṣe to lapẹẹrẹ si eto ilera, bẹẹ lawọn yoo ṣe afikun awọn ile iwosan alabọọde fun eto ilera to jiire kaakiri awọn ijọba ibilẹ ipinlẹ Eko.

O ni, “Akoko ti to bayii fawọn eeyan wa lati faaye gba ijọba mi-in lati gba eto iṣejọba lati le ṣẹgun inira to n ba awọn eeyan finra. Oriṣiiriṣii awọn eto la ti la kalẹ, eto ẹkọ, ironilagbara fawọn obinrin atawọn mi-in bẹẹ lo ti wa nilẹ. Nnkan tẹ ẹ nilo bayii ko ju bẹ ẹ ṣe maa bawọn eeyan sọrọ lori bi wọn yoo ṣe dibo fun wa, ka le baa jawe olubori lasiko ibo to wọle de yii”.

Yatọ si ile ijọsin ti Funkẹ lọ, obinrin yii tun lọ si awọn agbegbe to yi Ikorodu ka, awọn ilu bii Imọta, Odogunyan atawọn ibomi-in lati beere fun atilẹyin awọn eeyan gẹgẹ bi eto idibo ṣe n kanlẹkun.

Leave a Reply