Ibi to ba wu Sunday Igboho ko sa lọ, awa DSS yoo mu un

Faith Adebọla

“Ibi yoowu to ba wu Sunday Igboho ni ko sa lọ o, ṣugbọn ko le sa mọ awa agbofinro SSS lọwọ , a o mu un dandan ni.” Bayii ni awon DSS ṣe n sọrọ nigba ti wọn n ṣalaye bi ọwọ ko ṣe tẹ Igboho lasiko ti wọn kogun delẹ re laarin oru.

Wọn ni nigba ti awọn de ile rẹ ti awọn ẹṣọ ati awọn ọmolẹyin ẹ ti wọn wa ninu ile ẹ doju ibọn kọ awọn fun bii wakati kan ni ọkunrin ajijagbara naa ribi sa mọ awọn lọwọ. Ṣugbọn awọn ti dẹ gbogbo okun silẹ fun un awọn yoo si mu un laipẹ rara.

Niluu Abuja ti wọn ti n ṣafihan awọn mejila ti wọn lawọn fi pampẹ ofin gbe nile Sunday Igboho lawọn DSS ti sọrọ ọhun.

Agbẹnusọ awọn ọtẹlẹmuyẹ naa, Ọgbẹni Peter Afunaya, ni  olobo kan lo ta awọn pe Sunday Igboho atawọn eeyan kan to wa pẹlu rẹ ti ko awọn nnkan ija oloro jọ pelemọ sinu ile naa, lati fi ba ijọba ja, wọn ni wọn fẹẹ doju ijọba Naijiria de ni, to ba ya.

Afunaya ni ohun tawọn gbọ yii lo mu kawọn gbera lọọ gbọn ile rẹ yẹbẹyẹbẹ, kawọn si ṣewadii, o ni aago kan aabọ oganjọ oru lawọn de ile naa to wa lagbegbe Sọka, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.

O ṣalaye siwaju pe bawọn ṣe de’bẹ ni awọn ẹṣọ alaabo bii mẹsan-an to n ṣọ ile naa gboju agan soke sawọn, mẹfa ninu wọn lo gbe ibọn AK-47 dani, mẹta si gbe ibọn ibilẹ dani, ti wọn si fija pẹẹta pẹlu awọn, o ni wọn yinbọn sawọn awọn naa si fibọn dahun pada.

Ninu eruku ija ọhun to waye fun bii wakati kan nibọn ti ba awọn mẹta, meji ninu wọn dagbere faye loju ẹsẹ, ẹni kẹta tibọn ba lọwọ ọtun lawọn gbe lọọ gba itọju nileewosan kan nipinlẹ Ekiti, wọn lonitọhun ti n gbadun bayii.

O ni lẹyin tawọn ti ko awọn mẹfa to ku, lawọn raaye wọ ile naa, ṣugbọn o jọ pe Sunday Igboho ti raaye sa lọ, kawọn too wọle ọhun.

O lawọn eeyan ti wọn fi pampẹ ofin gbe nile naa ni Ọgbẹni Abdulateef Ofeyagbe, Amọda Babatunde ti inagijẹ rẹ n jẹ Lady ‘K’, Tajudeen Erinoyen, Diẹkọla Ademọla, Abideen Shittu, Jamiu Noah, Ayọbami Donald, Adelabe Usman, Oluwapelumi Kunle, Raji Kazeem, Taiwo Ọpẹyẹmi ati Bamidele Sunday.

Afunaya tun sọ pe nigba tawọn gbọn ile ile naa yẹbẹyẹbẹ, lara awọn nnkan ija oloro tawọn ba nibẹ ni ibọn AK-47 meje, ibọn ibilẹ mẹta, katiriiji ọta ibọn ti wọn o ti i yin ọgbọn, ẹgbẹrun marun-un ọta ibọn, ada marun-un, ọbẹ aṣoro kan, apo ti wọn n gbebọn si meji, digi ti wọn fi n wo ọna jinjin kan, pọọsi ti owo dọla marun-un wa ninu rẹ, lansẹsi iwakọ tilẹ yii ati toke okun ti orukọ Sunday Igboko wa lori rẹ, awọn kaadi ATM, iwe aṣẹ igbeluu orileede Germany to ni nọmba YO2N6K1NY lorukọ Sunday Igboho, feere ọlọdẹ meji, aadọta katiriiji ibọn ti ko si ọta ninu ẹ, ẹrọ ibanisọrọ tawọn ẹṣọ alaabo nlo mejidinlogun.

Wọn tun lawọn ba aṣọ oogun abẹnu gọngọ mẹta, kọmputa agbeletan meji, ati awọn pasipọọtu to jẹ tiẹ ati tawọn mi-in.

Ifunnaya tun sọ pe marun-un lara awọn ibọn AK-47 tawọn ri gba pada naa jẹ ti awọn ẹṣọ aṣọbode ati imigireṣọn ilẹ wa, wọn ni ọwọ wọn ni wọn ti ja a gba.

O ni iṣẹ iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ yii.

 

 

 

Leave a Reply