Ibo 2023: Awọn adari APC Ọṣun ko gbe esi idibo abẹle jade, wọn ni wọn fẹẹ kọwọ bọ ọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ara o rokun, ara o rọ adiyẹ, laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun lọwọlọwọ pẹlu bi awọn adari ẹgbẹ naa ṣe kọ lati kede esi idibo abẹle to waye lati ọsẹ to kọja.
Ọjọbọ, Tọsidee, iyẹn ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni wọn ṣe idibo abẹle fun awọn oludije sileegbimọ aṣofin, ilana eto idibo gbangba-laṣaa-ta ni wọn si ṣe lọsan-an ọjọ naa.
Bi wọn ṣe pari idibo ni wọọdu kọọkan ni wọn ti gbe esi idibo wa si olu ile ẹgbẹ wọn niluu Oṣogbo pẹlu ireti pe wọn yoo kede ẹni to jawe olubori nibẹ, ṣugbọn ijakulẹ ni wọn ba pade.
Nigba to tun di ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, wọn ṣeto idibo awọn ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin kaakiri ẹkun idibo mẹsan-an to wa kaakiri ipinlẹ Ọṣun, sibẹ, wọn ko ti i gburoo esi titi di asiko yii.
Ọjọ Satide ni wọn ṣe idibo ti awọn sẹnetọ, bẹẹ ni ko tun si esi. Ohun to mu ki wahala naa pọ ni pe gbogbo awọn alatilẹyin oludije kọọkan ni wọn ti n ki ẹni tiwọn ku oriire jijawe olubori.

Ahesọ to n lọ kaakiri ni pe ṣe lawọn adari ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun fẹẹ kọwọ bọ esi idibo naa, a gbọ pe pupọ lara awọn ti wọn fọkan si pe wọn yoo rọwọ mu ni wọn fidi rẹmi, idi niyi ti wọn ṣe n gbiyanju lati tun esi idibo naa kọ.
Ṣugbọn gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lawọn ibi ti ọrọ kan ni wọn ti kan’ro sinu, wọn ni ewu nla ni yoo jẹ ti Gomina Oyetọla ba faaye gba ẹnikẹni lati tọwọ bọ awọn esi idibo naa.
Koda, awọn ijọba ibilẹ kan ti fẹhonu han lọ si sẹkiteriati ẹgbẹ wọn niluu Oṣogbo, nigba ti awọn kan lọ sile Dokita Ajibọla Baṣiru to jẹ alakooso igbimo ipolongo saa keji Oyetọla lati lọọ sọ fun un pe awọn ọmọ ẹgbẹ ju oludije lọ.
Ni ti igun ẹgbẹ naa ti wọn n pe ara wọn ni The Ọṣun Progressives (TOP), wọn ni ṣe ni ki awọn alaṣẹ apapọ ẹgbẹ naa l’Abuja fagi le idibo naa patapata nitori ariwo lasan ni.
Ninu apilẹkọ ti agbẹnusọ awọn ti wọn dije lọdọ wọn, Ọnarebu Wasiu Adebayọ, ka lo ti sọ pe nnkan itiju nla, to si lodi si agbekalẹ ẹgbẹ onitẹsiwaju ti awọn n ṣe, ni ki wọn kuna lati ka esi idibo lẹyin odidi ọjọ marun-un.

O ni wọn ṣe lawọn kan jokoo sinu ile ijọba l’Oṣogbo, ti wọn si n kọ maaki ti wọn fẹ fun awọn oludije to ba wu wọn nitori wọn ko ṣamulo ohun ti wọn ka nibudo idibo kọọkan.
Yatọ si Adebayọ, awọn oludije yooku latinu TOP ni Ọwọade Ademọla Adeyẹmi, Wahab Kazeem Ọlanrewaju, Babalọla Iqmal Ọpeyẹmi, Kọlawọle Ọlalere Victor.
Awọn to ku ni Arabinrin Adeṣọla Arawọle Adegbitẹ, Ọlaoye Abdulhakeem, Arabinrin Ọlaniyi Shariat Olanikẹ, Kasali Nurudeen Adelaja, Ọpadọla Abdullahi Amọbi, Kọmọlafẹ Akinlabi Richard ati Ibrahim Oyekunle.

Leave a Reply