Ibo 2023: Ki Musulumi jẹ aarẹ ati igbakeji ẹ ko le ṣiṣẹ – Gumi

Faith Adebọla, Eko

Ilumọ-ọn-ka olukọ ẹsin Musulumu lapa Oke-Ọya ilẹ wa, Sheikh Ahmad Abubakar Gumi, ti kede pe ẹtan ati awuruju lasan lawọn oludije funpo aarẹ ati igbakeji aarẹ ti wọn jẹ ẹlẹsin kan naa fẹẹ ṣe faraalu, ẹtan naa ko si le wọle, tori ohun ti Naijiria nilo lasiko eto idibo gbogbogboo lọdun 2023 ni olori to ni iriiri, to si le so awọn eeyan pọ niṣọkan, ki i ṣe adari ti yoo fi ọrọ ẹsin fawọn eeyan loju mọra.

Gumi sọrọ yii lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an yii, ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe lọfiisi rẹ lede Hausa.

O ni ọrọ to delẹ yii ki i ṣe ọrọ ẹya tabi ti ẹsin, tori aye ọlaju la wa yii, a o si nilo adari ti ko niriiri.

Gumi ni: Adari to niriiri, to mọ ohun to n ṣe, ni Naijiria nilo, ki i ṣe eyi to ṣẹṣẹ fẹẹ dije funpo aarẹ. Bi nnkan ṣe ri ni Naijiria lọwọ yii nilo ẹni to le wa ojuutu si i.

“Ko tọna bi Tinubu ṣe sọ pe oun lo kan, ọrọ emi lo kan kọ lọrọ to delẹ yii. Ki i ṣe eeyan kan lo maa sọ pe oun lo kan, tori tawọn araalu ba fẹ ẹ ni wọn maa dibo fun un, ti wọn o ba fẹ ẹ, wọn o ni i dibo fun un. Ẹni to mọ eto ilu ni Tinubu loootọ, o si le ṣe e, ṣugbọn ko digba to ba yan Musulumi meji sipo aarẹ ati igbakeji.

Gbogbo wa la mọ p’awọn oloṣelu wọnyi n wa ibo ni, ṣẹ ẹ ri ọrọ yiyan Musulumi meji sipo, ẹ jẹ ki n sọ ọ lede Hausa, wayo ni, ẹtan ni. Ki i ṣe ifẹ ẹsin ni wọn ni. Boya o maa ṣiṣẹ tabi ko ni i ṣiṣẹ, ẹ ma jẹ ki n sọ asọtẹlẹ o, ṣugbọn ohun to wa lẹyin Ọfa ju Oje lọ. Ka sododo ọrọ, gbogbo ẹgbẹ oṣelu lo niṣẹ gidi lati ṣe, tori ọrọ aarẹ ẹlẹsin kan naa yii, ami ati apẹẹrẹ lo jẹ, boya apẹẹrẹ ta a le tẹle ni abi ki i ṣe eyi ta a le tẹle, a maa mọ laipẹ.

Ni ti ọrọ Peter Obi, awọn ọdọ to n tẹle e, ẹnu wọn o ko, bẹnu awọn agbalagba naa o ṣe ko. O gbọdọ lọọ bawọn agbaagba sọrọ, awọn ọdọ lo gbara le, iyẹn o dẹ le gbe e debikan, ọrọ oṣelu ki i ṣe ọrọ agbegbe kan.

Gumi ṣekilọ pe yiyan oloṣelu ti ko niriiri sipo agbara lo maa n mu ko ṣoro lati ko awọn alajọṣiṣẹ to maa ran an lọwọ jọ. O ran awọn ọmọ Naijiria leti pe odidi oṣu mẹfa ni Aarẹ Muhammadu Buhari lo ko too yan awọn minisita ati oṣiṣẹ ijọba ẹ, tori ko niriiri beeyan ṣe n ṣelu.

Ni ipari ọrọ ẹ, Gumi ni eto aabo to mẹhẹ yii ko le lojuutu ti iwa irẹnijẹ ati ipo oṣi to n ba awọn eeyan finra ko ba yanju.

CAPTION

Leave a Reply