Ibo aarẹ, eyi ni iṣẹ ti Baba Adebanjọ ran si ajọ eleto idibo

Ọrẹoluwa Adedeji

Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, Baba Ayọ Adebanjọ, ti ṣekilọ fun ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, pe ki wọn ma gbidanwo lati yi esi idibo to n lọ lọwọ yii ti wọn ko ba fẹ wahala.

Ninu ọrọ ti baba agbalagba to n ṣe atilẹyin fun Obi ati ẹgbẹ Labour yii sọ lo ti ni, ‘‘Awọn ọmọ Naijiria ti fi han pe awọn fẹ Peter Obi lati jẹ aarẹ wọn pẹlu bi wọn ṣe dibo fun un.

Ti ajọ eleto idibo ba waa gbiyanju lati yi ibo naa, ki awọn ọmọ Naijiria dide, ki wọn fi ẹhonu han gidigidi, ki ajọ agbaye le ba wọn da si i.

‘‘Ti ẹ ba mọ pe ẹ ko fẹ ọmọ ẹya Igbo gẹgẹ bii aarẹ Naijiria, ẹ kuku fi wọn silẹ ki wọn maa lọọ ṣe Biafra wọn’’.

Tẹ o ba gbagbe, latigba ti ipolongo ibo ti bẹrẹ ni olori ẹgbẹ Afẹnifẹre yii ti fi atilẹyin rẹ han fun Peter Obi, ọpọ ibi ti ọkunrin ọmọ bibi ilẹ Igbo naa ba si ti ṣe ipolongo ibo nilẹ Yoruba ni baba yii maa n tẹle e lọ.

Baba Adebanjọ sọ pe ti a ba fẹẹ pin in ni ilana pin-in-re, la-a-re, ẹya Igbo lo yẹ ki ipo aarẹ Naijiria kan, nitori awọn nikan ni wọn ko ti i ṣe e ri latigba ta a ti bẹrẹ ijọba awa-ara-wa. Eyi ni idi pataki ti baba na fi ni awọn n ṣatilẹyin fun Peter Obi ati ẹgbẹ Labour.

Leave a Reply