Monisọla Saka
Ninu igbẹjọ ẹsun idibo aarẹ to waye niluu Abuja, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Aarẹ Bọla Tinubu ati ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, ti Alaaji Atiku Abubakar ati Peter Obi fẹsun kan pe bi wọn ṣe kede ẹ pe o wọle ibo Aarẹ oṣu Keji, ọdun yii, ni ọwọ kan eru ninu, ti sọ fun ile-ẹjọ pe ki wọn ma ṣe gba awọn ẹri bii ojilelọọọdunrun ti Atiku ko wa sile-ẹjọ naa.
Oloye Chris Uche, ti i ṣe aṣaaju ikọ agbẹjọro fun Atiku ati ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), ṣalaye fun ile-ẹjọ pe ọwọ awọn ti pada tẹ awọn esi idibo aarẹ, eyi tawọn ri lori ẹrọ ayelujara ajọ INEC.
Esi idibo aarẹ ipinlẹ Abia, Bayelsa, Kaduna ati Ogun wa ninu iwe ti wọn gbe siwaju ile-ẹjọ, bẹẹ ni wọn tun mu ẹri wa lori abajade esi idibo nipinlẹ mẹtalelọgbọn lorilẹ-ede yii. Awọn ipinlẹ mẹrin ti wọn ni ko si nibẹ ni Kaduna, Katsina, Kano ati Eko.
Ṣugbọn olori ikọ agbẹjọro ẹgbẹ oṣelu APC ati Tinubu, Oloye Wolẹ Ọlanipẹkun, ta ko iwe tawọn PDP gbe siwaju ile-ẹjọ, wọn ni o da awọn loju pe bojuboju wa ninu ẹri ti wọn mu wa, ṣugbọn awọn ko ni i sọ idi tawọn fi ta ko o bayii, wọn ni ipade di inu ọrọ ẹjọ tawọn yoo kọ kẹyin.
Bakan naa ni Kẹmi Pinhero, ti i ṣe aṣaaju fawọn lọọya ajọ INEC, lodi si ẹri awọn PDP, gẹgẹ bii awọn olujẹjọ yooku. O ni oun ta ko alaye ti wọn ṣe pe ori itakun agbaye ajọ INEC lawọn ti ri i.
Onidaajọ Haruna Tsammani, to ṣaaju igbimọ awọn adajọ maraarun ti yoo ṣedajọ lori ẹsun naa gba ẹri tawọn PDP mu wa, o si ṣe akọsilẹ wọn pẹlu ami to pe ni ‘PT’, latori ikinni, titi dori mẹtalelọgbọn(PT1-PT33), eyi to mu ki gbogbo ẹri tawọn Atiku ati ẹgbẹ PDP ko siwaju ile-ẹjọ naa pe ojilelọọọdunrun-o-din-mẹta (337).