Ibo abẹle APC: Buhari tun wọle ipade pẹlu awọn gomina ilẹ Hausa

Adewumi Adegoke

Pẹlu bo ṣe ku wakati diẹ ki eto idibo abẹle lati yan oludije ti yoo ṣoju ẹgbẹ APC ninu ibo aarẹ ọdun to n bọ waye, Aarẹ Muhamadu Buhari ti tun wọle ipade mi-in pẹlu awọn gomina ilẹ Hausa.
ALAROYE gbọ pe eyi ni yoo jẹ ipade kẹrin ti Aarẹ yoo ṣe lati ri i pe wọn fẹnu ko lori ẹni kan ṣoṣo ti wọn yoo fa kalẹ lati dije dupo aarẹ nitori fa-a-ka-ja-a to le tidi rẹ yọ ti wọn ba gba gbogbo awọn oludije naa laaye lati kopa.
Awọn gomina ilẹ Hausa bii mẹtala la gbọ pe wọn ti de sibi ipade naa, nigba ti wọn ṣi n reti Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello, gẹgẹ bi iweeroyin Vanguard ṣe sọ.

Leave a Reply