Faith Adebọla
Olori awọn aṣofin apapọ ilẹ wa, toun naa wa lara awọn oludije fun tikẹẹti ẹgbẹ All Progressives Congress (APC), lati dupo aarẹ lọdun 2023, Ọmọwe Ahmed Lawan, ti rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn aṣoju ẹgbẹ naa, iyẹn awọn dẹligeeti ti wọn maa kopa ninu eto idibo abẹle APC lati yan oludije sipo aarẹ, o ni ki wọn yẹ itan ati akọọlẹ ẹni ti wọn fẹẹ dibo fun wo daadaa, ki wọn ma dibo fẹnikẹni to ba ti lẹbọ lẹru rara.
Ọrọ yii wa ninu lẹta jan-an-ran-jan-an-ran kan to kọ si wọn lọjọ Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹfa yii, eyi to wa ninu atẹjade kan to fi lede lori eto idibo abẹle naa.
Lawan ni nibi tọrọ de ninu ẹgbẹ APC ati eto oṣelu orileede yii, awọn aṣoju naa ko gbọdọ wo ti beeyan ṣe lowo lọwọ bii ṣẹkẹrẹ si, wọn o si gbọdọ dibo wọn fawọn to jẹ owo ni wọn gboju le lati fi tan wọn, o ni adari tootọ ni ki wọn yan, ki i ṣe oloṣelu.
Lẹta naa ka lapa kan pe:
“Si gbogbo ẹyin dẹligeeti ni gbogbo Naijiria, mo rawọ ẹbẹ si yin pe ki ẹ gbe ọrọ owo ju sẹgbẹẹ kan, ki ẹ ronu gidigidi lori ohun to maa dara ju lọ. Bi ẹ ṣe fẹẹ pinnu lori yiyan ẹni to maa di asia ẹgbẹ wa mu nipo aarẹ, mo rọ yin pe adari gidi ni kẹ ẹ wa, ki i ṣe oloṣelu kan.
“Ẹni to maa ṣaaju Naijiria ni kẹ ẹ yan, ki i ṣe ẹni ti yoo kan maa paṣẹ. Ẹni to maa loye, to maa ri ara gba nnkan si, ti ko ni i ṣojooro, to jẹ olootọ, ati ẹni to nifẹẹ ilọsiwaju ni kẹ ẹ wo. O si gbọdọ jẹ aṣaaju tọwọ ẹ mọ, ti ko ni kọlọfin kan, ti ko sẹbọ lẹru ẹ.
“Loootọ gbogbo awa ọmọ Naijiria lo yẹ ka fun eyi lafiyesi o, ṣugbọn ọdọ yin lo ti bẹrẹ, ẹyin aṣoju wa. Mo ṣeleri fun yin pe emi o ni i ja yin kulẹ. Mo bẹ yin kẹ ẹ fun mi ni ibo yin, kẹ ẹ si fọkan tan ẹgbẹ wa, APC, ati ilẹ wa, Naijiria. Mo ṣeleri pe tẹ ẹ ba fun mi ni tikẹẹti APC lati dupo aarẹ, ẹ maa fi mi yangan, pẹlu igboya, ifarada, igbagbọ, ipinnu ati ifọkansin.
“Awọn ẹni nla nla wa to ti lọ bii Alaaji Ahmadu Bello, Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ, Ọmọwe Nnamdi Azikiwe, Alaaji Abubakar Tafawa Balewa, Herbert Macaulay, Ọjọgbọn Eyo Ita, Alvan Ikoku, Oloye Anthony Enahoro, Egbert Udo Udoma, Alaaji Aminu Kano, Oloye S. A. Ajayi, Joseph Tarka, Oloye Sunday Awoniyi, Dennis Osadebay atawọn yooku n wo yin lati mọ ohun tẹ ẹ fẹẹ ṣe o”.