IBO AWỌN PDP L’ONDO: JẸGẸDẸ WỌLE, AGBOỌLA JA BỌ!

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Pẹlu gbogbo ilakaka Igbakeji Gomina Ipinlẹ Ondo, Ajayi Agboọla, lati koju  ọga rẹ, Rotimi Akledredolu, ninu ibo gomina ipinlẹ Ondo to n bọ ninu oṣu kẹwaa ọdun yii, gbangba ode ni wọn ti jan ẹyin ọkunrin naa mọle ninu ibo PDP ti wọn di kọja lanaa yii, nitori Eyitayọ Jẹgẹdẹ ni lawọn PDP Ondo fa kalẹ pe yoo du ipo gomina lorukọ ẹgbẹ wọn.

Agboọla mura kaka, o ja bii ọkunrin, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ ni. Nitori nigba ti wọn dibo tan, Jẹgẹdẹ lo ni ibo to pọ ju lọ. Ọrinlelẹgbẹrin ati mẹjọ (888) ibo ni Jẹgẹdẹ ni, nigba ti Agboọla si ni ibo ọtalelẹgbẹta o din meji (658) Eddy Ọlafẹsọ to ni ibo marundinlọgọsan-an (175) lo tẹle wọn, ibo marundinlọgọrun-un (95) ni ti Bọde Ayọrinde, Banji Okunọmọ ni aadọrun-un (90), Ṣọla Ẹbiṣeni ni mọkandinlọgbọn (29), Boluwaji Kunlerẹ ni mẹtalelọgbọn (33) ati Godday Erewa to ni ibo mẹrinla pere (14).

Awọn eeyan ti ro pe Agboọla ni yoo mu kinni naa, koda oun naa ti leri leka pe ko si ibi ti wọn yoo gbe e gba, oun loun yoo gba tikẹẹti PDP, oun yoo si wọle gegẹ bii gomina, nitori ninu ibo ti awọn di ni 2016, oun gan-an loun gbe Akeredolu ati APC wọle nibẹ. Ṣugbọn nigba ti ọkunrin naa ko waa wọle ibo abẹle yii nkọ o, nibo ni yoo gbe eyi gba!

Ẹkunrẹrẹ iroyin naa n bọ laipẹ.

 

Leave a Reply