Nitori Korona, Awujalẹ fagi le Ojude Ọba t’ọdun yii

Nitori arun aṣekupani Koronafairọọsi to gbode kan, Awujalẹ ilẹ Ijẹbu, Ọba Sikiru Adetọna ti kede pe ayẹyẹ ‘Ojude Ọba’ to maa n waye lẹyin ọdun Ileya ko ni i waye lọdun yii. Kabiyesi ni ki onikaluku jokoo sile rẹ.

Ninu atẹjade kan to wa lati aafin, eyi ti Baagbimọ ilẹ Ijẹbu, to tun maa n ṣe kokaari eto naa, Oloye Fassy Yusuf, fi sita lo ti sọ pe Ọba (Dokita) Sikiru Adetọna fọwọ si fifagile ayẹyẹ naa lẹyin amọran latọdọ awọn eleto ilera, ati bi ohun gbogbo ko ṣe fara rọ lori ọrọ ajakalẹ arun Korona to gbode kan.

Leave a Reply