Ibo gomina Eko: Sanwo-Olu fagba han GRV ati Jandor

Faith Adebọla

Gomina Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu ti wọle ibo sipo gomina ipinlẹ Eko fun saa ẹlẹẹkeji, latari bi wọn ṣe kede rẹ p’oun lo jawe olubori ninu eto idibo to waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta yii, to si fẹyin awọn ti wọn jọ ta kan-an-gbọn ninu ibo ọhun janlẹ.

Gbọgbọọgbọọ bọwọ ṣe n yọ ju ori ni ibo ti Sanwo-Olu, lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ni fi tayọ tawọn ẹlẹgbẹ rẹ, Gbadebọ Rhodes-Vivour, ti wọn n pe ni GRV lẹgbẹ oṣelu Labour Party, to wa nipo keji, ati Ọlajide Adediran tawọn eeyan mọ si Jandor, to wa nipo kẹta.

Nigba ti oludari eto idibo naa nipinlẹ Eko, Oluṣẹgun Agbaje, n kede esi ibo naa ni deede aago kan kọja iṣẹju mẹẹẹdogun, oru ọjọ Aje, Mọnde, ogunjọ, oṣu Kẹta yii, o ni ninu ijọba ibilẹ ogun to wa nipinlẹ Eko, Sanwo-Olu gbegba oroke nijọba ibilẹ mọkandinlogun, nigba ti Rhodes-Vivour fakọyọ nijọba ibilẹ kan.

Lara awọn ijọba ibilẹ ti ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgọta naa ti rọwọ mu, ti wọn ti rọ obitibiti ibo fun un ni Ikẹja, Apapa, Badagry, Lagos Island, Ẹpẹ, Agege, Ibẹju-Lekki, Koṣọfẹ, Surulere ati Ṣomolu

Bakan naa ni nnkan ṣẹnuure fun Sanwo-Olu ni Ajeromi-Ifẹlodun, Ifakọ-Ijaiye, Lagos Mainland, Alimọṣọ, Ọjọọ, Ikorodu, Mushin and Oshodi, pẹlu aropọ ibo ẹgbẹrun lọna ọtalelẹẹẹdẹgbẹrin o le meji (762,134).

Ẹgbẹ Labour mu jawe olubori ni ijọba ibilẹ kan ṣoṣo, iyẹn Amuwo-Ọdọfin, amọ aropọ ibo wọn jẹ ọọdunrun le mejila ati diẹ (312,329) ti wọn si wa nipo keji.

Jandor ko ri ijọba ibilẹ kankan mu, amọ o ni aropọ ibo ẹgbẹrun lọna mejilelọgọta o le irinwo (62,449).

Lara ohun to mu ki ikede esi idibo naa pẹ ko too pari ni pe idibo ṣi n lọ lọwọ lawọn ibudo idibo mẹwaa kan lagbegbe Victoria Garden City, VGC, ni Lẹkki, l’Erukuṣu Eko, ọjọ Sannde yii lawọn ṣẹṣẹ dibo tiwọn, wọn si ni lati duro di aṣaalẹ ti wọn pari eto idibo ọhun ki wọn le ro gbogbo ẹ papọ, amọ Sanwo-Olu naa lo gbegba oroke nibẹ.

Pẹlu ikede yii, Sanwo-Olu, to jẹ gomina kẹrin nipinlẹ Eko latigba ti eto iṣejọba oloṣelu ti bẹrẹ pada lọdun 1999 yoo ṣe saa ọdun mẹjọ lori aleefa, gẹgẹ bii tawọn aṣaaju rẹ, Bọla Ahmed Tinubu ati Babatunde Faṣọla, ti ọkọọkan wọn lo saa meji, ti i ṣe ọdun mẹjọ-mẹjọ, ayafi Arẹmọ Akinwunmi Ambọde, to lo saa kan ọlọdun mẹrin, iyẹn ni 2015 si 2019

 

Leave a Reply