Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Pẹlu bi igbẹjọ lori eto ibo to waye nipinlẹ Ọṣun ninu oṣu Keje, ọdun yii, ti n tẹsiwaju, ẹlẹrii ti ajọ eleto idibo (INEC), pe lati jẹrii lori awọn ẹsun ti gomina ana, Gboyega Oyetọla ati ẹgbẹ rẹ, APC, pe ta ko jijawe olubori Gomina Ademọla Adeleke, sọ niwaju igbimọ olugbẹjọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, osu Kejila, ọdun yii, pe o da bii ẹni pe adiju-ibo wa lawọn apa kan.
Ẹlẹrii naa, Abimbọla Ọladunjoye, sọ pe ijọba ibilẹ Ọṣogbo loun ti ṣiṣẹ lọjọ idibo naa gẹgẹ bii oluṣakoso imọ ẹrọ (Technical Supervisor).
Ṣaaju ni ajọ INEC ti ko maṣinni aṣayẹwo, iyẹn Bimodal Voters Accreditation System (BIVAS) ẹgbẹrun kan o din mẹrinlelogun (976) to jẹ ti awọn agbegbe ti Oyetọla ti fi ẹsun magomago ibo kan wa sile-ẹjọ fun ayẹwo.
Agbẹjọro INEC, Ọjọgbọn Paul Ananaba (SAN), ko awọn iwe to jẹ Forms EC8A-E kalẹ niwaju igbimọ naa pẹlu awọn maṣinni naa, eyi ti ile-ẹjọ gba gẹgẹ bii ẹsibiiti fun igbẹjọ yii.
Nigba ti Barisita Ananaba, agbẹjọro Adeleke, Onyechi Ikpeazu (SAN) ati agbẹjọro PDP, Alex Izinyon (SAN), kọkọ n gba ọrọ lẹnu Ọladunjoye, o ni ajọ INEC ko ti i ṣakojọ (Synchronize) ohun to wa ninu BIVAS tan ko too di pe wọn ko esi idibo fun awọn olupẹjọ.
O ni ẹrọ BVAS, Fọọmu EC8A ati iwe akọsilẹ awọn oludibo ni akọsile to yanrannti lori ohunkohun to ba waye nibudo idibo kọọkan latijọba ipinlẹ titi de wọọdu.
Nigba ti agbẹjọro olupẹjọ, Akin Olujinmi (SAN) n beere ibeere lọwọ Ọladunjoye, o ni oun ki i ṣe oṣiṣẹ to ṣakoso eto idibo naa (presiding officer), o ni lẹyin ti wọn kede esi idibo loun too buwọ lu ojulowo akọsilẹ (CTC) naa.
Nigba ti wọn sọ pe ko wo akọsilẹ ẹri to kọ nile-ẹjọ ṣaaju (witness statement) ati esi idibo to wa ninu nnkan to buwọ lu (CTC) ni Guusu Ẹdẹ, o ni “o da bii ẹni pe adiju ibo marundinlọgọrin wa nibẹ”
Ni wọọdu miran, o ni, “Ibo ọrinlelẹgbẹrin o din mẹwaa (830) ni mo kọ silẹ, ṣugbọn ẹgbẹrin o din meje (793) lo wa ninu akọsilẹ. O da bii ẹni pe adiju ibo mẹtadinlogi wa nibẹ”.
“Ninu abala 26.7 iwe akọsilẹ eri mi, irinwo ati meji lo wa ninu akọsilẹ orukọ awọn oludibo, ibo ọtalelugba o le mẹta ni wọn kọ sinu akọsilẹ BIVAS. O da bii ẹni pe adiju ibo ogoje o din ẹyọ kan wa nibẹ.”
Nigba ti wọn beere idi to fi n lo “o da bi” ninu gbogbo idahun rẹ, Ọladunjoye ṣalaye pe lero toun, gbogbo ayẹwosira (comparison) ti yoo ba waye gbọdọ wa laarin Fọọmu EC8A ati ẹrọ BIVAS. O ni, “gẹgẹ bii ofin INEC, inu ẹrọ BIVAS la ti le ri iye awọn oludibo ti wọn ṣayẹwo fun ati awọn ti wọn dibo, akọsilẹ rẹ yoo si tun wa ninu Fọọnu EC8A.”
Lẹyin eyi ni ajọ INEC sọ pe awọn ko ni ẹlẹrii kankan lati pe mọ. Bẹẹ ni awọn igbimọ olugbẹjọ paṣẹ pe ki wọn ma ṣe da awọn ẹrọ BIVAS pada si sakaani ajọ INEC, ṣugbọn ki wọn gbe wọn lọ sile ifowopamọ apapọ ilẹ wa (CBN).