Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ọmọdekunrin ẹni ọdun mọkanlelọgọrin kan, Akeem Banji, ti wa ni atimọle ọlọpaa bayii niluu Ado-Ekiti, nibi to ti n ṣalaye ohun to sun un debi ẹsun ole ti wọn fi kan an fun awọn ọlọpaa.
Ọmọkunrin to n ṣiṣẹ birikila naa lọwọ ọlọpaa tẹ laduugbo Ekute, niluu Ado-Ekiti, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lori ẹsun pe o lọọ fibọn ka ọkunrin kan, Ayọdeji Oluṣọla, mọ ṣọọbu rẹ lọsan-an ọjọ naa, to si gba ẹgbẹrun lọna aadọta naira lọwọ rẹ.
Bakan naa ni awọn agbofinro ni o tun ko awọn ẹru mi-in yatọ si owo yii ninu ṣọọbu rẹ, to si halẹ mọ ọn pe oun yoo yinbọn lu u to ba pariwo.
Ṣugbọn bi Banji ṣe gba owo naa tan to si n gbiyanju lati ko awọn ẹru to ji ninu ṣọọbu naa lọ ni awọn ọlọpaa de si adugbo ọhun, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn soke. Lasiko naa ni wọn mu ọmọkunrin yii.
Awọn agbofinro gba owo ati gbogbo ẹru to ko ni ṣọọbu ọkunrin oniṣowo naa, bẹẹ ni wọn tun gba ibọn ilewọ agbelẹrọ kan lọwọ rẹ.
Nigba to n ṣalaye fawọn ọlọpaa, Banji ni oun ati awọn ẹlẹgbẹ oun meji, Oyinbo ati Ayo, ti wọn ti sa lọ bayii, lawọn jọọ waa ṣiṣẹ naa.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe Banji to jẹ olori awọn ọdaran naa ti wa ni atimọle awọn, iwadii si ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa. O ni awọn yoo wa awọn yooku kan, ti wọn yoo si foju wina ofin.