Ibọn onike ni John fẹẹ fi gbowo lọwọ oni-POS n’Ikorodu tọwọ fi tẹ ẹ

Faith Adebọla, Eko

Ọwọ palabi ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlogoji kan ti se’gi n’Ikorodu, o ti dero ahamọ ọlọpaa ni Panti, Yaba, nipinlẹ Eko, latari bo ṣe n fibọn onike ṣeru ba awọn eeyan, to n si n ja wọn lole owo ati dukia wọn kọwọ too tẹ ẹ.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, nnkan bii aago kan aabọ ọsan ogunjọ, oṣu yii, lafurasi ọdaran ti wọn lo n gbe adugbo Alejẹ, lagbegbe Ikorodu, ọhun lọọ yọbọn si ọmọbinrin kan to n fi ẹrọ POS ṣiṣẹ nibi tiyẹn ti n ṣọrọ aje ẹ, lọkunrin yii ba ni ko ko owo to pa foun, aijẹ bẹẹ oun maa yinbọn fun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejọbi,  ṣalaye ninu atẹjade to fi ṣọwọ si wa pe John ti ṣiṣẹẹbi ẹ tan kawọn bọisi adugbo kan ti wọn fura nipa iṣẹlẹ naa too lọọ rẹbuu ẹ, ti wọn si mu un.

Lẹyin ti wọn din dundu iya fun un diẹ ni wọn lo jẹwọ pe ibọn toun fi n ṣiṣẹ adigunjale ki i ṣe ibọn gidi, ibọn onike ni, o kan jọra pẹlu ojulowo ni.

Eyi lo mu ki wọn kan si teṣan ọlọpaa Ikorodu tawọn yẹn fi wa, ni wọn ba fa ọkunrin adigunjale naa le wọn lọwọ.

Wọn ni bi kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko ṣe gbọ nipa iṣẹlẹ yii lo ti paṣẹ pe ki wọn tarari afurasi ọdaran naa si Panti, lọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ, ibẹ lawọn ti wọn maa beere ọrọ lọwọ ẹ wa, oun naa si ti n ṣalaye fun wọn.

Wọn lọkunrin naa maa too kawọ pọnyin niwaju adajọ laipẹ.

Leave a Reply