Monisọla Saka
Aarẹ orilẹ-ede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti ki ileeṣẹ to n ri si ọrọ epo rọbi nilẹ wa, Nigeria National Petroleum Company Limited (NNPCL), ku oriire, lori igbedide ibudo ifọpo to wa niluu Port Harcourt, nipinlẹ Rivers ọhun.
Tinubu ni ki wọn yawọ si iṣẹ lori bi wọn yoo ṣe tete pari iṣẹ atunṣe ati igbedide ibudo ifọpo Port Harcourt keji, ati eyi to wa ni Warri ati Kaduna bakan naa.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni Bayọ Ọnanuga, ti i ṣe oludamọran pataki si Aarẹ lori eto iroyin, sọrọ yii di mimọ, ninu atẹjade to fi lede niluu Abuja.
Ninu atẹjade to pe akọle rẹ ni ‘Aarẹ Tinubu ṣe ajọyọ igbedide ibudo ifọpo Port Harcourt’, lo ti ni, “Aarẹ mọ riri ipa ribiribi ti Aarẹ ana, Muhammadu Buhari, ko ninu ṣiṣe agbekalẹ eto bi wọn yoo ṣe tun awọn ibudo ifọpo wa ṣe, bẹẹ lo tun fẹmi imoore han si ile ifowopamọ African Export-Import Bank, fun igbẹkẹle ti wọn ni ninu wa lati kowo silẹ fun iṣẹ akanṣe yii lati jẹ ṣiṣe.
“Siwaju si i, Aarẹ Tinubu gboṣuba nla fun adari ileeṣẹ NNPCL, Ọgbẹni Mele Kyari, ti ẹmi ifọkansin rẹ jẹ ọna kan gboogi ti wọn fi bori adojukọ lati mu eleyii wa si imuṣẹ.
“Pẹlu bi wọn ṣe ri ibudo ifọpo Port Harcourt yii tun ṣe, Aarẹ Tinubu rọ ileeṣẹ NNPC ki wọn mura si iṣẹ lori bi wọn yoo ṣe gbe ibudo ifọpo keji to wa niluu Port Harcourt ati eyi to wa ni Warri pẹlu Kaduna dide.”.
Ka ranti pe lọdun 2023, labẹ iṣejọba Aarẹ Buhari, ni igbesẹ lati tun awọn ibudo ifọpo wa ṣe bẹrẹ. Bi ilẹ Naijiria ṣe jẹ ọga ninu awọn orilẹ-ede to ni epo rọbi to, agbẹkẹle wa ko kuro ninu rira epo wọle lati Oke-Okun.
Bo tilẹ jẹ pe apa meji ni ibudo ifọpo ipinlẹ Rivers ni, ti eyi to jẹ ti atijọ, ti wọn kọ lọdun 1965 yoo maa gbe ẹgbẹrun lọna ọgọta agba epo jade lojumọ, ti ikeji ti wọn kọ lọdun 1989, yoo si maa gbe agba epo bẹntiroolu to to ẹgbẹrun lọna aadọjọ (150,000 barrels), jade lojumọ nigba ti wọn ba pari isẹ lori rẹ.
Apapọ mejeeji yoo si to igba agba epo ati mẹwaa, (210 barrels) ni mejeeji yoo maa pese lojumọ.
Banki ilẹ Afrika to n ri si oko-owo rira ọja wọle ati tita a si ilẹ okeere, African Export-Import Bank, lo gbe biliọnu kan aabọ Dọla (1.5 billion dollar), kalẹ, fun iṣẹ atunṣe ibudo ifọpo naa.
Amọ to jẹ pe idaduro ọlọkan-o-jọkan to de ba iṣẹ ti wọn kede pe o ti pari nibẹrẹ ọdun 2024 yii, lo sọ ọ di eyi to ṣẹṣẹ pari bayii.
Ọgọta ẹgbẹrun agba epo, ni wọn ni ibudo ifọpo naa ni ikapa lati maa pese lojumọ kan, bẹrẹ lati ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Aarẹ Tinubu ni gbogbo akitiyan ileeṣẹ NNPC yii yoo ran awọn ileeṣẹ to n pese nnkan lorilẹ-ede yii lọwọ, ti yoo si sọ ilẹ Naijiria di ọkan gboogi lara awọn orilẹ-ede to n pese epo.
O ni erongba ijọba oun ni lati tun awọn ibudo ifọpo orilẹ-ede yii ṣe, lati le fopin si ibanujẹ to wa ninu pe Naijiria to ni epo rọbi ko le fọ ọ funra wọn lati lo.