Idajọ de! Sotitobirẹ atawọn marun-un mi-in n lọ ẹwọn gbere

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Adajọ Ile-ẹjọ giga to wa l’Akurẹ ti ni ki oludasilẹ ijọ Sọtitobirẹ, Alfa Babatunde atawọn osiṣẹ rẹ marun-un lọọ fẹwọn gbere jura lori ọrọ ọmọ ọdun kan to sọnu ninu sọọsi rẹ, iyẹn Gold Ẹninlaloluwa, ninu oṣu kọkanla, ọdun to kọja.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lonii, ọjọ Isẹgun, Tusidee, Onidaajọ Olusẹgun Oduṣọla ni gbogbo ẹri ti wọn fi siwaju ile-ẹjọ lo fidi ẹ mulẹ pe wọn jebi ẹsun mejeeji ti i ṣe ijinigbe ati ṣiṣe iranlọwọ lati ji ni gbe, eyi ti wọn fi kan wọn.

Adajọ ọhun tun fi aidunnu rẹ han si iwa odalẹ ati agbẹyinbẹbọjẹ tawọn ọlọpaa hu lori iwadii ọmọdekunrin ọhun lasiko to ṣẹṣẹ di awati.

2 thoughts on “Idajọ de! Sotitobirẹ atawọn marun-un mi-in n lọ ẹwọn gbere

Leave a Reply