‘Idajọ ododo la fẹ lori Abass ti wọn yinbọn pa sinu oko rẹ n’Iwoo’

Florence Babaṣọla

Awọn ọdọ ilu Iwo, nipinlẹ Ọṣun, ti ke si ileeṣẹ ọlọpaa lati fi panpẹ ofin mu ẹni to pa ọkan lara wọn, Abass Adewale, lasiko wahala ọrọ ilẹ to waye laarin ilu Iwo ati Ile-Ogbo lọsẹ to kọja.

Ṣe ni wọn n fi ọkọ agbegilodo (Truck) gbe oku ọmọkunrin naa kaakiri ilu Iwo lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ti wọn si n pariwo pe ọkan lara awọn ọmọlẹyin Olu Ile-Ogbo lo yinbọn pa a.

Tẹ o ba gbagbe, lasiko wahala ọhun kan naa ni ọkan lara awọn ẹṣọ aafin ọba Olu ti Ile-Ogbo ṣeesi yinbọn pa kọpura ọlọpaa to n ṣọ kabiesi naa.

Ṣugbọn gẹgẹ bi ọkan lara awọn ọdọ ilu Iwo, Oladoṣu Adio, ṣe ṣalaye, ọlọpaa kan (orderly), lara awọn to maa n tẹle Olu Ile-Ogbo, Ọba Habeeb Agbaje, Nurein, lo yinbọn lu Abass lori ninu oko rẹ lọjọ keje, oṣu karun-un, ọdun yii.

O ni oloogbe naa ni oko kan to n da nibi ilẹ to n da wahala silẹ laarin awọn ilu mejeeji naa, ati pe ṣe lo n ṣiṣẹ lọwọ ninu oko rẹ lọjọ yii ti Nurein fi yinbọn lu u, latigba naa lo si ti wa nileewosan, ko too di pe o jade laye nidaaji ọjọ Iṣẹgun, Tusidee.

Agọ ọlọpaa to wa ni Adẹẹkẹ, niluu Iwo, ni wọn kọkọ gbe oku Abass lọ, nibẹ si ni ọlọpaa kan ti ba wọn sọrọ, to si parọwa si wọn lati lọọ sin oku naa, pẹlu ileri pe idajọ ododo yoo waye lori ọrọ yii.

Lẹyin eyi ni wọn lọọ sinku oloogbe ọhun nilana ẹsin Islam, to si jẹ pe ariwo idajọ ododo ni wọn n pa nibẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, ni wọn fẹsun kan Nureni pe o yinbọn lu oloogbe ọhun, ko too di pe o dagbere faye laaarọ Tusidee.

O ṣalaye pe ẹgbọn Abass, Gbọla Fasasi, lati agboole Ashipa, niluu Iwo, lo lọọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti pe ọkan lara awọn to n tẹle Olu Ile-Ogbo, Nureni, yinbọn lu u lori, ti wọn si n tọju rẹ lọsibitu, nibi to ti gbẹmi-in mi.

Leave a Reply