Idajọ ododo la fẹ lori awọn tọọgi to ba ileeṣẹ burẹdi wa jẹ n’Iwo – Taawun

Florence Babaṣọla

Agbarijọ ẹgbẹ awọn Musulumi kan niluu Iwo, Jama’at Taawunil Muslimeen, ti sọ pe afi ki awọn tọọgi ti wọn huwa janduku nileeṣẹ burẹdi kan niluu Iwo lopin ọsẹ to kọja finmu danrin ofin, aijẹ bẹẹ, ṣe lawọn yoo fọn soju titi fẹhonu han.

Akọwe iroyin wọn, Lukman Salaudeen, sọ pe ṣe lawọn tọọgi naa lu awọn ti wọn n ṣiṣẹ nileeṣẹ Albadir Bakers, niluu Iwo, lalubami, ti wọn si ba awọn irinṣẹ ti wọn n lo nibẹ jẹ.

Ohun to ṣẹlẹ gẹgẹ bo ṣe sọ ni pe ẹgbẹ awọn oniburẹdi kede pe ọmọ ẹgbẹ awọn kankan ko gbọdọ dana burẹdi lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, nitori wọn fẹẹ fi owo le owo burẹdi.

Ṣugbọn yatọ si pe ẹgbẹ Taawun lo ṣe iforukọsilẹ ileeṣẹ burẹdi Albadir, eleyii to tumọ si pe ẹgbẹ oniburẹdi lapapọ ko lagbara lori wọn, Salaudeen sọ siwaju pe ileeṣẹ naa ko fẹẹ fi aye ni awọn araalu lara rara, idi niyẹn ti wọn ko ṣe fẹẹ fi owo kun owo burẹdi tiwọn.

O ni bi wọn ṣe dana burẹdi tan lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, ni awọn tọọgi ọhun ya de, wọn lu gbogbo awọn oṣiṣẹ atawọn ti wọn waa ra burẹdi laaarọ ọjọ naa, koda, alubami ni wọn lu obinrin alaboyun kan ti wọn ba nibẹ.

Salaudeen fi kun ọrọ rẹ pe ada (cutlass) ni awọn tọọgi ọhun ko wa sibẹ, ti wọn si ṣa awọn eeyan naa yanna-yanna, eeyan marun-un lo si tipasẹ iṣẹlẹ naa deleewosan.

O ni loootọ ni ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ mẹfa lara awọn ti wọn huwa laabi naa, ṣugbọn ohun ti awọn fẹ ni idajọ ododo, wọn ko gbọdọ fi wọn silẹ lai ṣe pe wọn foju winna ofin ijọba nitori ẹgbẹ to ba wu onikaluuku lo le darapọ mọ labẹ ofin orileede Naijiria.

Ninu ọrọ tirẹ, Alaga ẹgbẹ awọn oniburẹdi l’Ọṣun, Alhaji Ganiyu Bakare, sọ pe awọn ti yanju wahala naa.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn kan latari iṣẹlẹ naa, o ni Kọmiṣanna Wale Ọlọkọde ko ni i faaye gba ẹnikẹni lati huwa ti ko bofin mu nibikibi.

 

Leave a Reply