‘Idi ti a fi ti ileewe aladaani bii ẹgbẹta pa nipinlẹ Ọṣun ree’

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Kọmiṣanaa fun eto ẹkọ nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Fọlọrunṣọ Bamiṣayemi, ti sọ pe, o kere tan, ileewe aladaani to to ẹgbẹta ti wọn ko wa nibaamu pẹlu ilana ijọba lawọn ti ti pa bayii.

Lasiko to n jabọ iṣẹ iriju rẹ fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Wẹsidee, ọsẹ yii, lo ṣalaye pe igbesẹ naa pọn dandan lati le ri i pe ayika to dara lawọn akẹkọọ ti n kẹkọọ, to si jẹ pe awọn olukọ ti wọn kunju oṣuwọn ni wọn n kọ wọn nibẹ.

O ni ọrọ eto-ẹkọ to peye jẹ ijọba logun pupọ, idi si niyi tijọba ko fi ni i faaye gba ẹnikẹni lati sọ awọn akẹkọọ di alaabọ-ẹkọ.

Bamiṣayemi sọ siwaju pe awọn ko ni i fojuure wo ileewe ti ko ba ni ayika to dun un kẹkọọ, bẹẹ ni olukọ ti ko ba kunju oṣuwọn ko le kọ awọn ọmọ ni ẹkọ to dara.

O ni, “A mọ bo ṣe ṣe pataki to ki ipilẹ ẹkọ awọn ọmọ duroore, ti ipilẹ ba ti wọ, yoo ṣoro lati mọ nnkan to lagbara le e lori. Idi niyi ti a ko ṣe fi ọwọ yẹpẹrẹ mu awọn oludasilẹ ileewe aladaani.

“Oniruuru ẹka la ti ṣedasilẹ rẹ nileeṣẹ eto ẹkọ, awọn kan ti wa lati maa lọ kaakiri fun amojuto awọn ileewe aladaani ati tijọba.

“Ẹnikẹni to ba fẹẹ da ileewe silẹ nipinlẹ Ọṣun gbọdọ ni iwe-ẹri TRCN atawọn nnkan amuyẹ yooku, ko saaye dida ileewe silẹ tori pe o ri owo lojiji.

“Oniruuru igbekalẹ la ti ni, iru ẹni bẹẹ si gbọdọ yege ki a too fọwọ si i pe ko da ileewe silẹ’

Kọmiṣanna yii fi kun ọrọ rẹ pe mimu atunṣe ba oriṣiiriṣii ilana iṣejọba to kọja lori eto ẹkọ ti n so eso rere pupọ, o si ṣeleri pe gbogbo awọn araalu ni wọn yoo yin Gomina Oyetọla lawo lẹyin iṣejọba rẹ nipasẹ awọn aṣeyọri ti yoo ṣe lẹka eto ẹkọ.

 

Leave a Reply