Idi ti oludije fun’po aarẹ fi gbọdọ wa lati Aarin-Gbungbun Ariwa ilẹ wa ni 2023 ree-Baraje 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ nilẹ yii, Alaaji Abubakar Kawu Baraje, ti sọ idi pataki ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi gbọdọ gbe ipo aarẹ si ẹkun idibo Aarin-Gbungbun orilẹ-ede yii ni ipo aarẹ ti gbọdọ wa lọdun 2023.

Lasiko ti Baraje n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Ilọrin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, lo ṣe ẹkunrẹrẹ alaye lori rẹ. O ni ti a ba fẹẹ pin in dọgba-n-dọgba lẹka eto oṣelu, ẹkun naa lo kan to yẹ ko jẹ aarẹ lọdun 2023, tori pe latigba ti Naijiria ti gbominira kuro lọwọ awọn oyinbo amunisin, wọn o ti i jẹ aarẹ ni ẹkun naa. Fun idi eyi, ọ yẹ ki wọn fun wọn ni anfaani lati pese aarẹ lọdun 2023, bo tilẹ jẹ pe awọn to n pe fun gbigbe ipo aarẹ si ẹkun naa ko tun gbọdọ polongo pupọ ki orile-ede Naijiria ma baa pin yẹlẹyẹlẹ.

Baraje sọ pe ọrọ ti igbekeji aarẹ tẹlẹ nilẹ wa, to tun jẹ oludije sipo naa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2019, Alaaji Atiku Abubakar, sọ nipa gbigbe ipo naa kaakiri ẹkun kọọkan nilẹ wa, ootọ ni, sugbọn o ti gbagbe pe wọn ti ṣe atunse si iwe ofin ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun to kọja, to si ti wa ninu iwe ofin ẹgbẹ naa bayii, ti wọn si ni gbogbo ọmọ ẹgbẹ gbọdọ bọwọ fun ofin gbigbe ipo naa kaakiri awọn ekun to wa ni Naijiria.

 

Leave a Reply