Idibo ku si dẹdẹ, alaga ẹgbẹ PDP atawọn mi-in darapọ mọ ẹgbẹ APC l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ni bayii ti ibo gomina ipinlẹ Ọṣun ku ọjọ mejidinlogun, alaga igun kan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọgbẹni Wale Ojo, igbakeji Sẹnetọ Ademọla Adeleke lasiko idibo ọdun 2018, Oloye Albert Adeogun, oludije funpo ileegbimọ aṣoju-ṣofin ninu ẹgbẹ PDP, Ayọdele Asạlu, atawọn mi-in ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC bayii.
Nibi ipolongo ibo ti ẹgbẹ oṣelu APC ṣe niluu Oṣogbo lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lawọn eeyan ọhun ti sọ pe awọn ti sa kuro ninu ẹgbẹ Ọlọnburẹla, nitori ẹgbẹ naa ko ni eto rara.
Wale Ojo ni alaga igun ẹgbẹ oṣelu PDP l’Ọṣun ti wọn dibo abẹle tiwọn ni gbọngan WOCDIF, niluu Oṣogbo, nibi ti Ọmọọba Dọtun Babayẹmi ti jawe olubori gẹgẹ bii oludije funpo gomina. Latigba naa ni ẹjọ si ti wa laarin Babayẹmi ati Adeleke nile-ẹjọ giga ijọba apapọ ilu Oṣogbo.
Nigba to n gba igbalẹ, Wale Ojo ṣalaye pe ẹni ti ko ba mọ nnkan to n ṣe nikan ni yoo ṣi jokoo sinu ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ọṣun, o ni oniruuru ipa tiṣejọba Gomina Oyetọla ti ni laarin ilu ti fi i han gẹgẹ bii ọlọpọlọ pipe to ni imọ kikun nipa iṣejọba.
O ni Oyetọla duro fun idagbasoke ati iṣerere.

Bakan naa lọrọ ri lẹnu Adeogun, o ni iṣejọba Oyetọla ti mu alaafia wa sinu ipinlẹ Ọṣun, ẹni to ba si dibo fun un fun saa keji dibo fun ominira ni.

O ni lai fi ti owo perete to n wọle sasunwọn ijọba ṣe, Oyetọla tun n ṣe oniruuru iṣẹ akanṣe kaakiri ipinlẹ Ọṣun. O fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo nnkan ti awọn lo lati fi polongo ibo ta ko ẹgbẹ APC lọdun 2018 ni Oyetọla ti yanju bayii.

Nigba to n gba awọn ti wọn darapọ mọ wọn, Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore gboriyin fun igbesẹ akin ti gbogbo wọn gbe lati darapọ mọ ẹgbẹ Onitẹsiwaju, o ṣeleri fun wọn pe wọn ko ni i kabaamọ igbesẹ wọn.
Bakan naa ni Gomina Oyetọla gboṣuba fun wọn lori ipinnu wọn lati ṣiṣẹ papọ pẹlu ẹgbẹ APC fun aṣeyọri idibo ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii.

Leave a Reply