Idigunjale Ọffa: Eyi ni ba a ṣe yinbọn pa eeyan mọkanla 

Stephen Ajagbe, Ilorin

Mẹrin ninu awọn afurasi marun-un to n jẹjọ lori iṣẹlẹ idigunjale banki ilu Ọffa, eyi to waye lọjọ karun-un, oṣu kẹrin, ọdun 2018, ṣalaye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, fun ile-ẹjọ giga kan niluu Ilọrin pe ohun to mu awọn yinbọn pa eeyan mọkanla ni pe wọn n ju okuta atawọn nnkan mi-in lu awọn lasiko tawọn n ja banki lole.

Awọn afurasi maraarun naa ni; Ayọade Akinnibosun, Ibikunle Ogunlẹyẹ, Adeọla Abraham, Azeez Salawu ati Niyi Ogundiran.

Agbẹjọro fun ijọba, Ọgbẹni Rotimi Jacob, ke pe ẹlẹrii keje, iyẹn Insipẹkitọ John Nwoke, to jẹ ayaworan fun olu ileeṣẹ ọlọpaa lapapọ, lati jẹrii lori ẹjọ naa.

Nwoke fi fọnran kan silẹ niwaju ile-ẹjọ, ninu eyi ti gbogbo ọrọ ti wọn gba lẹnu awọn afurasi naa wa.

Ninu fidio naa, awọn mẹrẹẹrin, yatọ si Ayọade Akinnibosun, lo jẹwọ pe loootọ lawọn yinbọn pa awọn mọkanla to n ju nnkan lu awọn.

Ni ti Ayọade Akinnibosun, o ni Michael Adikwu to jẹ ọlọpaa nigba kan, ṣugbọn to ti doloogbe bayii, lo fi idigunjale naa lọ oun, lẹyin naa loun fi to awọn ẹgbẹ oun mẹrin leti, tawọn jọ lọọ ṣiṣẹ naa.

Afurasi naa tẹsiwaju ninu fọnran ọhun pe oun ni adari ikọ idigunjale naa, oun loun ni awọn ọkọ mejeeji tawọn fi lọ soko ole.

O ṣalaye pe ọkan lara awọn ọkọ naa, jiipu Lexus SUV, gomina ana nipinlẹ Kwara, Abdulfatah Ahmed, lo fi ro oun lagbara gẹgẹ bii adari ikọ ipolongo oṣelu eyi ti wọn n pe ni ‘Political Liberation Movement’, lẹkun Kwara South.

 

Leave a Reply