Ọlawale Ajao, Ibadan
Idije imọ Ede Yoruba to le sọ awọn akẹkọọ ileewe girama di miliọnia yoo bẹrẹ ninu oṣu kẹrin, ọdun 2022 yii kaakiri ileewe girama nilẹ Yoruba, Kogi ati Kwara nibi ti awọn akẹkọọ ati ileewe to ba yege yoo ti gba ẹbun owo ati oriṣiiriṣii nnkan mi-in.
Ibudo Ajọ Agbaye (Yoruba World Centre) lo ṣagbekalẹ eto naa, ọdọọdun nidije ọhun yoo si maa jẹaye.
Gbogbo ipinlẹ ta a ti le ba iran Yoruba pade lorileede yii ni wọn ni ifigagbaga imọ yii ko sinu. Iyẹn ni pe bo ṣe kan ipinlẹ Ọyọ, Eko, Ọṣun, Ogun, Ondo ati Ekiti ni ko yọ awọn ipinlẹ bii Kwara ati Kogi paapaa silẹ.
Afojusun eto yii, ta a pe akori ẹ ni “ASIKO LATI PE AWỌN ỌDỌ WA TO TI SỌNU SINU AṢA ATỌHUNRINWA PADA” ni lati fun awọn akẹkọọ ati ileewe wọn lanfaani lati fi ẹbun owo atawọn nnkan meremere ṣefa jẹ.
Ninu ipade ti igbimọ ajọ Yoruba Agbaye ṣe pẹlu awọn adari Ẹgbẹ Akọmọlede Yoruba nilẹ yii, atawọn olukọ ede Yoruba kaakiri awọn ileewe girama gbogbo ni wọn ti kede igbesẹ ti yoo sọ awọn akẹkọọ doloriire yii. Gbogbo alaga ẹgbẹ Akọmọlede ni gbogbo awọn ipinlẹ taa ti darukọ ṣaaju, titi dori aarẹ ẹgbẹ naa jake-jado orileede yii ni wọn peju-pesẹ sibi ipade nla ọhun.
Eto idije imọ Yoruba ọlọdọọdun ti ajọ Ibudo Yoruba Agbaye gbe kalẹ yii ni yoo maa waye pẹlu ajọṣepọ ijọba ilẹ Yoruba gbogbo, nitori awọn ileeṣẹ to n mojuto eto ẹkọ lawọn ijọba ipinlẹ kaakiri ilẹ Kaaarọ-o-jiire-bi naa wa ninu awọn agbatẹru eto yii.
Gẹgẹ bi alakooso ajọ Yoruba World Centre, Ọgbẹni Alao Adedayọ, to fidi iroyin yii mulẹ ṣe sọ siwaju, ileeṣẹ to jẹ ajumọni awọn ijọba ilẹ Yoruba, (Odu’a Investment Company Plc.) ati DAWN Commission, iyẹn ajọ to n ri si eto idagbasoke ilẹ Yoruba naa wa lara awọn to ṣagbatẹru eto nla naa.
Ọgbẹni Adedayọ fi kun un pe lati ijọba ibilẹ ni idije naa yoo ti maa bẹrẹ, ki awọn to ba jawe olubori nijọba ibilẹ kọọkan too jọ figagbaga. Lẹyin naa lawọn to ba ṣe ipo kin-in-ni ni ipinlẹ kọọkan yoo jọ na an tan bii owo ninu aṣekagba idije ti yoo sọ ẹni to ba fakọyọ ju lọ di miliọnia yii.
‘‘Ta o ba gbagbe, laipẹ yii ni Igbakeji Aarẹ orileede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, awọn gomina, awọn ọba ilẹ Yoruba, atawọn saraki saraki ọmọ Oodua ṣe ifilọlẹ Yoruba World Centre. Yoruba World Centre ta a si wi yii, ọkan lara ọmọ ti ajọ kan ti awọn oloyinbo n pe ni International Centre for Yoruba Arts and Culture (INCEYAC) bi ni i ṣe.
“Mo ranti daadaa pe lara iṣẹ ta a pinnu lati maa fi ajọ INCEYAC ṣe ni lati pe awọn ọdọ wa to ti ba aṣa atọhunrinwa lọ pada, iṣẹ ọhun naa la ti bẹrẹ yii, ka le ti asiko yii fi ipilẹ rere lelẹ fun ọjọọwaju iran wa”. Bẹẹ l’Ọgbẹni Adedayọ to tun jẹ Oludasilẹ ileeṣẹ iweeroyin ALAROYE ṣe sọ.
Gẹgẹ bii atupalẹ ti baba naa ṣe, o ni, “Lọwọlọwọ yii, akẹkọọ to n wọle sileewe girama kaakiri ilẹ Yoruba ati ni Kwara pẹlu ipinlẹ Kogi lọdọọdun ju miliọnu kan lọ. Apapọ awọn akẹkọọ to wa nileewe girama pata le ni miliọnu marun-un. Taa ba waa da awọn akẹkọọ wọnyi sọna ọgọrun-un, awọn ojulowo ọmọ Yoruba, to jẹ pe nilẹ Yoruba la bi wọn si, ju ida aadọrun-un (90) lọ. Ba a ba waa le ra awọn ọmọ ọlọpọlọ pipe to ti ba aṣa alaṣa lọ wọnyi pada sinu aṣa wa, dajudaju, iran Yoruba ko ni i ṣai jẹ iran oloriire ju lọ lorilẹ aye.
“Iran Yoruba yoo ṣoriire nitori igbesẹ ta a dawọ le yii ko ni i jẹ ki ede wa parun. Bakan naa, yoo lana fun ipese iṣẹ, ironilagbara fawọn ọdọ, ati paapaa, iṣọkan ati igbọra-ẹni-ye laarin awọn ẹya gbogbo to wa ni Naijiria wa yii.
“Nitori idi eyi, ojuṣe wa ni lati ṣe koriya fawọn ọdọ wa lati maa sọ ede Yoruba, ki wọn si maa fi ede naa kọ nnkan silẹ. Awọn akitiyan taa ko jọ sinu idije imọ Yoruba taa gbe kalẹ ọhun naa ree ki awọn akẹkọọ wa le ni imọ kikun nipa ede ati aṣa Yoruba.