Faith Adebọla
Sinkin bii ẹni jẹ tẹte oriire lawọn ọmọ orileede Morocco atawọn ololufẹ bọọlu afẹsẹgba nilẹ Africa wa bayii latari bi ẹgbẹ agbabọọlu orileede adulawọ naa, Atlas Lions of Morocco, ṣe fitan balẹ, wọn fẹyin akẹgbẹ wọn lati orileede Portugal balẹ pẹlu ami ayo kan dondo, ni ipele quarter final, wọn si jawe olubori si ipele to kangun si aṣekagba, iyẹn semi-finals, fun igba akọkọ ninu idije ife -ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ lorileede Qatar, eyi si ni igba akọkọ ti orileede ilẹ Afica eyikeyii yoo de ipele latigba ti idije ife-ẹyẹ agbaye ti bẹrẹ lọdun mejilaaadọrun-un sẹyin.
Ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye lọsan-an ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹjila, ọdun 2022 yii, ni papa iṣere Al-Thumama, ni Morocco ti gbo ẹwuro soju Portugal, nigba ti agbabọọlu wọn, Youssef En-Nesyri, fi tẹri si bọọlu kan ti wọn gba si i latoke ni iṣẹju mejilelogoji ti wọn bẹrẹ ayo naa, ori lo fi bọọlu naa wọle ṣọọ bii elekurọ, sinu awọn Portugal, ariwo ayọ ati atẹwọ si gba papa iṣere naa kan.
Nigba ti wọn bẹrẹ apa keji ifẹsẹwọnsẹ naa, bawọn agbabọọlu Portugal ṣe n ṣiṣẹ aṣekara lati ri i pe awọn da gbese ayo kan yii pada, bẹẹ lawọn ti Morocco n ṣiṣẹ aṣelaagun, lati ri i pe awọn jẹ kinni naa lajẹgbe ti igun n jẹbọ, Ifa si fọre fun wọn, titi ti iṣẹju marundinlaaadọta ipele keji, ati afikun iṣẹju mẹfa ti wọn fun wọn si i fi pe, akitiyan Portugal ko seeso rere pẹẹ, bọọlu wọn ta ku, ko wọle sawọn.
Ọrọ naa kọja sisọ, ilumọ-ọn-ka agbabọọlu agbaye nni, Christiano Ronaldo, ti wọn gbe wọle nigba ti apa keji ifẹsẹwọnsẹ bẹrẹ pe boya yoo le pitu ẹṣẹ rẹ, ti yoo si kọ awọn alatako lọgbọn, ko le mu un mọra mọ nigba ti rẹfiri fọn feere ipari, niṣe lo doju bolẹ, to bu sẹkun gbaragada, ṣe arokan ni i fa ẹkun asun-i-dakẹ, bẹẹ lọpọ lara awọn agbabọọlu Portugal ati awọn alatilẹyin wọn fajuro bii ẹni ọfọ nla ṣẹ, pupọ ninu wọn lo sunkun asunwa bii ọmọ kekere.
Ohun to tubọ gbomi loju wọn ti ọrọ naa fi ka wọn lara to bẹẹ ni pe ko sẹni to reti pe orileede ilẹ Africa bii Morocco ni yoo fọwọ osi juwe ọna ile fun ẹgbẹ agbabọọlu to lookọ bii Portugal, niṣe lọrọ naa da bii ẹni ta o ro pe yoo pagọ, to kọle alaruru. Morocco sọ alagbara di ọlẹ, eyi si ni igba akọkọ lati ọdun 1966, iyẹn ọdun mẹrindinlọgọta sẹyin, ti Portugal yoo pade idena to ju ẹmi ẹ lọ lati kọja si ipele semi-finals.
Tẹ o ba gbagbe, Morocco lo na Belgium lami ayo meji sodo, wọn na Canada lami ayo meji si ẹyọ kan, wọn si ta ọmi pẹlu Croatia, nigba ti idije yii bẹrẹ, eyi ti wọn fi sọda si ipele awọn agbabọọlu mẹrindinlogun to peregede. Wọn fiya nla jẹ Spain ni ipele yii, ami-ayo mẹta si odo ni wọn fi fẹyin Spain janlẹ, eyi si ni wọn ba sọda si ipele quater finals, nibi ti wọn ti pade Portugal lọjọ Satide yii, ti wọn si fọna ilu Lisbon, olu-ilu orileede wọn han wọn.
Orileede Cameroun lọdun 1990 ati Senegal lọdun 2002 lo ti i de ipele quater finals ri nilẹ Africa, ajẹmọ wọn ko si ju bẹẹ lọ ri, niṣe ni wọn n ku sọna bii eefin.
Ni bayii, Morocco ti wa ni sẹpẹ lati pade eyikeyii orileede to ba jawe olubori laarin England tabi France, ki wọn too mọ boya wọn yoo tẹ siwaju si ipele aṣekagba.
Amọ ṣa o, wọn ni ohun to ba jọhun la a fi wehun, eepo ẹpa lo jọ posi ẹliri, imin adigbọnranku si jọ talabahun. Awọn kan lara awọn alatilẹyin oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi, ti foju ọtọ wo aṣeyọri Morocco yii o, itumọ mi-in lawọn si fun un lori ẹrọ ayelujara. Wọn ni owe nla ni aṣeyọri naa n pa fawọn ẹgbẹ oṣelu alagbara ni Naijiria, paapaa APC ati PDP, wọn ni bi Morocco ṣe ṣohun torileede Africa kan o ṣe ri, ti wọn fẹyin awọn agbabọọlu to nikimi balẹ lairoti, wọn ni kawọn ẹgbẹ oṣelu ti wọn ro pawọn nifọn leekan lọọ maa mura silẹ, ohun to maa ṣẹlẹ ninu eto idibo 2023 to n bọ yii, afaimọ lọrọ yoo fi yatọ si ti Portugal, ibi ti wọn o foju si lọrọ naa maa ba yọ, gẹgẹ bi wọn ṣe wi o.