”Igbẹ lawọn Fulani to ya wọ lbarapa waa dẹ lati ipinlẹ Kebbi”

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọpọ èèyàn niṣẹlẹ ọhún ko laya soke nigba ti iroyin lu jade pe awọn Fúlàní daran-daran ko ọpọlọpọ ibọn atawọn ohun ìjà oloro mi-in wọ ipinlẹ Ọyọ wa.

Awọn ẹṣọ eleto aabo ilẹ Yoruba, Amọtẹkun, ẹka ipinlẹ Ọyọ ni wọn mu awọn Fúlàní mẹtala ohun tawọn tibọn pẹlu oríṣìíríṣìí nnkan ìjà oloro mi-in lọwọ wọn.

Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yìí, lawọn Amọtẹkun da wọn duro lalafo ilu Ilaju sí Eruwa, ninu ọkọ bọọsi wọn ti nọmba ẹ jẹ TUR 40 ZY (Kẹbbi).

Èyí ló mú ki awọn eeyan máa sá kíjokíjo fún ipaya ni ireti pe niṣe lawọn àjèjì náà yóò máa fi awọn nnkan ijagun naa pa awọn ara ipinlẹ yii nipakupa.

Èyí kò ṣẹyin oríṣìíríṣìí iṣẹlẹ ipaniyan to ti waye lemọlemọ lagbegbe Ibarapa lẹnu ọsẹ bíi meji sẹyin to si jẹ pe awọn Fúlàní wọnyi naa lọpọ eeyan sí gbà pé wọn wà nídìí ọwá ọdaran naa.

Ṣugbọn Ajagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanju ti i ṣe adari ẹṣọ Amotekun ni ipinlẹ Ọyọ ti fi awọn ara ipinlẹ naa lọkan balẹ pe awọn Fúlàní naa ko wa sí ipinlẹ yii lati jà tabi paayan, bi ko ṣe lati ṣọdẹ ẹranko.

Gẹgẹ bó ṣe sọ, “Awọn oṣiṣẹ wa lagbegbe Ido ati Eruwa ni wọn mu awọn Fúlàní yẹn, ṣugbọn iṣẹ ọdẹ ni wọn waa ṣe ni ipinlẹ yìí, wọn ko wa lati paayan tabi ṣe ẹnikẹni nibi.

“Iwadii wa fidi ẹ mulẹ pe ọdẹ lawọn eeyan yẹn, ati pe ìgbẹ́ ni wọn ti ipinlẹ Kebbi wá sí ipinlẹ Ọyọ waa dẹ lati pa ẹranko nínú igbókígbó ta a ba ti fẹẹ pẹran ni ipinlẹ yìí, nitori aja marundinlaaadọta (45) ni wọn kò lọwọ. Bẹẹ ni kaadi idanimọ to fi wọn han gẹgẹ bii ọdẹ wa lọwọ kaluku wọn.”

O waa fi awọn ara ipinlẹ naa lọkan balẹ lati máa ba iṣẹ oojọ wọn lo lai foya, nitori gbogbo agbara ni Amọtẹkun maa ṣa lati ri í pé aabo to péye wa fún gbogbo èèyàn ati dukia wọn.

 

Leave a Reply