Ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun ti wọn fi kan Oloye Rahman Adedoyin to ni Hilton Hotel and Resorts, to wa niluu Ileefẹ ti kọ lati gba beeli ọkunrin naa atawọn ọmọọṣẹ rẹ mẹfa ti wọn jọ fẹsun kan wọn.
Ni ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni igbẹjọ naa waye nile-ẹjọ giga kan niluu Oṣogbo, nibi agbẹjọro Adedoyin ati tawọn ọmọọṣẹ rẹ ti bẹ kootu pe ki wọn fun awọn eeyan naa ni beeli ki wọn ti ile waa maa jẹjọ wọn, ki wọn si le raaye lọọ tọju ara wọn.
Adajọ ile-ẹjọ giga naa, Onidaajọ Adepele Ojo, sọ pe ẹsun ti wọn fi kan awọn eeyan naa lagbara debii pe eeyan ni lati ṣọ ọ ṣe ki wọn too fun wọn ni beeli.
Yatọ si eyi, Ojo ni aisan to n ṣe awọn eeyan naa ko ju ohun ti ileewosan to wa ni ọgba ẹwọn le mojuto lọ, nitori naa, ọrọ naa ko to oun ti wọn le tori rẹ fun wọn ni beeli.
O fi kun un pe awọn olujẹjọ naa ko ni ẹri to daju lati sọ pe ọgba ẹwọn ko ni awọn ohun eelo to to lati tọju wọn.