Igbeyawo Akinọla tu ka lẹyin ogun ọdun, o lọmọ ale loun n ba iyawo oun tọ

Faith Adebọla, Eko

 “Niwọn igba tẹyin mejeeji ti gba lati lọ lọtọọtọ, ti ẹ o si nifẹẹ ajọgbe yin mọ, ko si ṣiṣe ko saiṣe ju pe ki ile-ẹjọ yii tu yin ka lọ. Tori naa, ile-ẹjọ yii paṣẹ pe igbeyawo laarin Akinọla Ikudọla ati Funṣọ Ikudọla ti wa sopin, ẹyin mejeeji ki i ṣe tọkọ-taya mọ lati oni lọ.”

Adajọ ile-ẹjọ kọkọ-kọkọ to wa lagbegbe Igando, nipinlẹ Eko, lo fa iwe igbeyawo kan ya bẹẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, wọn tu tọkọ-taya ọhun kan.

Ọkọọyawo, Ọgbẹni Akinọla Ikudọla, ẹni ọdun marundinlaaadọrin (65), lo wọ iyawo rẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgọta (56) lọ sile-ẹjọ naa loṣu to kọja, o loun nifẹẹ iyawo oun mọ, oun fẹẹ pin gaari pẹlu rẹ. O fẹsun kan iyawo rẹ ọhun, Abilekọ Funṣọ Ikudọla, pe oniṣekuṣe, alagbere paraku ati opurọ buruku ni, o ni niṣe lobinrin naa lọọ gbe oyun ale waa ka oun mọle, toun o si tete fura.

“Nigba to sọ fun mi pe oun loyun, mo ni ki i ṣe emi ni mo loyun tori o ti pẹ temi pelu ẹ ti jọ laṣepọ, o ti ju ọdun meji lọ. O bimọ naa loootọ, ṣugbọn ko pẹ tọmọ ọhun fi ṣalaisi.

“Akọbi wa obinrin ṣẹṣẹ pari ileewe sẹkọndiri ni o, ṣugbọn oriṣiiriṣii ọkunrin lo n tẹle e wale, bi ọkan ṣe n jade lomi-in n wọle, mo si sọ funyawo mi pe ko ba a wi, ṣugbọn ko dahun, kaka bẹẹ, ija lo maa maa ba mi ja. Ẹ o le gbagbọ pe odidi oṣu mẹta niyawo mi fi yọnda pe ki ọmọbinrin wa maa lọ sun ti ọkunrin nigboro.” Bẹẹ lọkunrin naa rojọ ni kootu, o tun ni iyawo oun maa n jale, o maa n ji oun lowo daadaa.

Nigba ti wọn ni kiyawo naa fesi sawọn ẹsun wọnyi, Funṣọ ni oun o tiẹ fẹẹ rojọ rara tori ọrọ ọkọ oun ti su oun, ọrọ igbeyawo naa si ti yọ lọkan oun pata. O ni ṣaago to n bu igo lọkọ oun pẹlu bo ṣe jẹ pe oloju ko-mu-o-lọ ni, gbogbo obinrin lo maa n ṣe ṣina pẹlu ẹ.

“Odidi ọdun meje ni ko fi gori mi, ko ṣi mi laṣọ wo, nigba ti mo si sọ ọ titi ti ko dahun, mo dọgbọn fi ọti tan an tori lankẹ ọmu ni, alẹ ọjọ kan ti mo rọ ọ lọti yo tan la jọ laṣepọ. Oun ni baba awọn ọmọ mi, emi o yan ale o, ṣugbọn alaibikita ẹda ni, ifẹ ẹ ti yọ lọkan emi naa,” Funṣọ lo ro’jọ bẹẹ.

Ṣa, Adajọ Adeniyi Kọledoye ti tu wọn ka, wọn paṣẹ pe kawọn ọmọ meji to ku wa lọdọ iya wọn, ki Akinọla si maa fi ẹgbẹrun mẹwaa naira ṣọwọ si wọn loṣooṣu fun ounjẹ. Wọn tun ni ko fun obinrin naa ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira (N300,000), ko le lọọ gba ilem ko si le bẹrẹ okoowo kan.

Leave a Reply