Igun meji lo dibo oloye ẹgbẹ ninu APC l’Ọṣun, awọn tọọgi da ti awọn alatilẹyin Arẹgbẹṣọla ru

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ṣe ni iro ibọn n dun lakọlakọ lọsan-an ọjọ Abamẹta, Satide, lasiko tawọn tọọgi kan ya bo ibi ti awọn igun kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn n jẹ The Osun Progressives (TOP) ti ṣeto idibo lati yan alaga atawọn oloye ẹgbẹ to ku.

Agbegbe Ladsol, loju-ọna Ogo-Oluwa, niluu Oṣogbo, ni wọn ti ṣeto idibo tiwọn. Sadeede lawọn tọọgi kan ya debẹ ni nnkan bii aago kan ọsan, ti wọn si n yinbọn soke lakọlakọ.

Ṣugbọn gudugudu awọn Sifu Difẹnsi ti wọn n ṣeto aabo fun wọn nibẹ ko tura silẹ, awọn naa dana ibọn pada si wọn, lasiko yii la gbọ pe ibọn ba meji lara awọn TOP, ti wọn si n gbatọju lọwọ nileewosan.

Idi niyi ti alaga awọn igun naa, Refrẹndi Adelọwọ Adebiyi, ṣe ke si Aarẹ Buhari ati awọn ọmọ igbimọ afun-nṣọ ẹgbẹ naa lati da si wahala to n lọ l’Ọṣun.

Adebiyi ṣalaye pe ki i ṣe igba akọkọ niyi ti awọn tọọgi yoo wa da wahala silẹ ninu ipade TOP, gbogbo eyi ni wọn si n ṣe lati fi ba awọn lorukọ jẹ.

Ninu ọrọ tirẹ, alaga tuntun ti awọn TOP yan lati tukọ ẹgbẹ oṣelu APC l’Ọṣun fun saa yii, Ọnarebu Rasaq Ṣalinṣile, ṣalaye pe erongba oun ni bayii toun ti di alaga ni lati mu ẹgbẹ naa pada bọ sipo, lati jẹ ki igbẹkẹlẹ ti awọn araalu ni ninu ẹgbẹ APC pada, ki ọrọ ẹgbẹ naa ma baa di itan nipinlẹ Ọṣun.

Ṣalinṣile sọ pe ipo ti ẹgbẹ APC wa l’Ọṣun bayii ba eeyan lọkan jẹ pupọ, bi awọn ti wọn si tukọ rẹ sẹyin ṣe huwa lo fa a, ṣugbọn pẹlu awọn oloye tuntun yii, omi tuntun ti ru, ẹja si ti wọnu rẹ.

Lara awọn ti wọn tun yan ni Alhaji Azeez Adeṣiji ti wọn kede bii igbakeji alaga, Ọnarebu Adelani Baderinwa lo di akọwe ẹgbẹ, Dokita Akinlabi Kọmọlafẹ ni igbakeji akọwe, Ọnarebu Akintoyeṣe Ademọla ni akapo, Arabinrin Ogundare Aina Funkẹ si di olori awọn obinrin.

Ẹgbẹ APC Ọṣun tun dibo yan Famọdun gẹgẹ bii alaga wọn fun saa keji

 

Leave a Reply