Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Latari ede aiyede to n waye lemọlemọ laarin awọn agba Musulumi kan ati Imaamu agba ile-ijọsin ọhun, Alaaji Abubakri Abass, ijọba ipinlẹ Ondo ti ti mọṣalaasi nla ilu Ikarẹ-Akoko pa.
Ipinnu yii waye ninu ipade igbimọ to n aṣejọba, eyi ti wọn ṣe lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
Awọn igbimọ ọhun la gbọ pe wọn gbe igbesẹ yii lati dena rogbodiyan to le fẹẹ su yọ lori ija agba meji to n fi gbogbo igba waye laarin imaamu agba atawọn agba Musulumi mọṣalaasi naa.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe ijọba n reti pe ki awọn tọrọ kan, iyẹn awọn ẹgbẹ imaamu, awọn alaafaa atawọn igbimọ Musulumi niluu Ikarẹ-Akoko ba wọn yanju ede aiyede naa, ki mọṣalaasi ọhun too le di ṣiṣi pada.
Lati ọdun to kọja ni ọkan-o-jọkan wahala ti n waye laarin awọn agba Musulumi kan ati Alaaji Abubakri to jẹ Imaamu agba mọṣalaasi nla tilu Ikarẹ, leyii to ṣokunfa bijọba ṣe ti ile-ijọsin ọhun pa fun igba diẹ.
Ko ṣeni to tun gbọ ohunkohun mọ lori ọrọ naa titi di Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ti iṣẹlẹ ọhun tun ba ọna mi-in yọ pẹlu iwe kan ti wọn fi ṣọwọ si imaamu naa pe awọn ti yọ ọ nipo, ati pe ko si anfaani fun un lati maa ṣaaju irun kiki ninu mọṣalaasi naa mọ.
Ki ọrọ yii ma tun di wahala nla ti yoo di rogbodiyan laarin ilu nijọba kuku kede pe awọn ti ti i pa.