Aderohunmu Kazeem
Wahala buruku lo n ṣẹlẹ lọwọ bayii lagbegbe Owode si Mile 12 l’Ekoo.
Wọn ni bi wọn ṣe n ba motọ jẹ, bẹẹ ni wọn n fọ ṣọọbu kiri.
ALAROYE gbọ pe niṣe lawọn eeyan n fi mọto wọn silẹ, ti kaluku si bẹrẹ si i sa asala fun ẹmi wọn.
Awọn eeyan ti n ke si awọn ẹṣọ agbofinro lati tete waa pana iṣẹlẹ ọhun.