Ija n bọ l’Ọṣun o: Awọn ọmọ Arẹgbẹṣọla ati Oyetọla tun fẹẹ gbena woju ara wọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ara ko r’okun, bẹẹ ni ara ko rọ adiyẹ bayii laarin awọn alatilẹyin gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ati awọn alatilẹyin Gomina Gboyega Oyetọla, ogun abẹle si n lọ lọwọlọwọ laarin wọn.

Lati oṣu to kọja nijọba Oyetọla ti n sọ pe awọn yoo ṣe ayẹyẹ ọdun meji ti awọn de ori aleefa nipinlẹ Ọsun, wọn ṣe alakalẹ oniruuru eto pẹlu ṣiṣi awọn iṣẹ akanṣe kọọkan ti wọn ti ṣe pari.

Lojiji ni awọn alatilẹyin Arẹgbẹṣọla bẹrẹ si i sọ kaakiri pe ọga awọn naa yoo ṣe ayẹyẹ ọdun kẹwaa ti ile-ẹjọ gba ipo gomina lọwọ ẹgbẹ PDP l’Ọṣun, to si gbe e fun Arẹgbẹṣọla.

Ohun to ya awọn araalu lẹnu ni pe ọsẹ yii kan naa lawọn mejeeji fẹẹ ṣe gbogbo eto naa. A gbọ pe Arẹgbẹṣọla ko ba Oyetọla sọrọ nipa eto to fẹẹ ṣe, dipo bẹẹ, ṣe lo lọọ gba aṣẹ lọdọ awọn alakooso ẹgbẹ naa l’Abuja pe oun fẹẹ ṣe e l’Ọṣun.

Idi niyi ti awọn alatilẹyin awọn alagbara mejeeji ṣe n sọ pe kaka keku ma jẹ sese, ṣe lo maa fi ṣawadanu, bi awọn ti Oyetọla ṣe n sọ pe ẹnikan ki i kere nidii nnkan rẹ, lawọn ti Arẹgbẹṣọla n sọ pe ẹfọ ki i le ẹfọ lawo.

Lati le fi idi ahesọ yii mulẹ, Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla ṣabẹwo si alaga akọkọ fẹgbẹ oṣẹlu APC lorileede yii, Oloye Bisi Akande, nile rẹ to wa niluu Ila lopin ọsẹ to kọja lai jẹ ki Gomina Oyetọla mọ, sẹnetọ to n ṣoju awọn eeyan Aarin-Gbungbun Ọṣun, Ajibọla Baṣiru, nikan lo lọọ pade Arẹgbẹ nibẹ.

A gbọ pe ọjọ naa ni Arẹgbẹṣọla sọ fun Baba Akande pe ko si ẹni to le da oun duro, oun yoo ṣe ayẹyẹ naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii. Bo tilẹ jẹ pe Akande sọ fun un pe ko sun tiẹ siwaju diẹ, sibẹ, wọn ni minista yii sọ pe ko si nnkan to jọ ọ.

Ninu ọrọ ti ọkan lara awọn to sun mọ Arẹgbẹṣọla bii iṣan-ọrun kọ sori fesibuuku rẹ laaarọ oni fi han pe wahala nla n bọ. Ọkunrin ọmọ bibi ilu Ondo naa sọ pe “Gbogbo yin lẹ maa mọ ibi ti a ti fẹẹ ṣe e ko too di ọjọ Wẹsidee.

“Ọgbẹni bori ọga agba lẹnu iṣẹ ologun (Army General) lati di gomina nigba ti ko di ipo kankan mu rara. Ki i ṣe ibẹru ija ni yoo da ayẹyẹ ọdun kẹwaa yii duro rara. Yala ki wọn darapọ mọ wa lati ṣe ayẹyẹ yii lalaafia, ki ohun gbogbo si lọ deede, tabi ki wọn rin jinna sibẹ, ka si ṣe eto tiwa lai ni idiwọ. Alaafia la ba wa o”

Gbogbo eleyii lo n mu ibẹru wa lọkan gbogbo awọn ti wọn ti n hu ọrọ naa gbọ pe ki lo le ṣẹlẹ ti eto mejeeji fi maa waye lọsẹ yii, wọn si n pe gbogbo awọn to moju Arẹgbẹ ati Oyetọla lati tete da si ọrọ naa, ki wahala ti ẹnikẹni ko ro tẹlẹ ma bẹrẹ nipinlẹ Ọṣun.

One thought on “Ija n bọ l’Ọṣun o: Awọn ọmọ Arẹgbẹṣọla ati Oyetọla tun fẹẹ gbena woju ara wọn

  1. Adura ni a o gba ki Olorun petu si arin awon asiwaju wayi, Awon omo egbe wa kookan wa lara awon tio o ngbe iro kiri larin awon Oga wa yi, nitori ijekuje ti won nwa kiri,

Leave a Reply