Ija Oyetọla ati Arẹgbẹṣọla: Ẹgbẹ APC Ọṣun tun da kọmiṣanna tẹlẹ fọrọ ijọba ibilẹ atoye jijẹ duro

Florence Babaṣọla

O da bii ẹni pe ọrọ ti wọn n pe lowe tẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun ti n ni aro ninu bayii pẹlu bi wọn tun ṣe kede idaduro Ọnarebu Kọlapọ Alimi, ẹni to jẹ ọkan pataki lara awọn ololufẹ gomina ana, Ọgbẹni Rauf Adesọji Arẹgbẹṣọla.

Agbẹjọro ni Alimi, oun si ni kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ lasiko iṣejọba Arẹgbẹṣọla nipinlẹ Ọṣun. Ọmọ bibi ilu Ẹrin-Ọṣun yii jẹ ọkan pataki lara awọn ti wọn wa ninu ‘The Osun Progressives [TOP]’ ti Arẹgbẹṣọla ṣefilọlẹ rẹ laipẹ yii.

Ninu lẹta idaduro rẹ ti ALAROYE ri, awọn oloye ẹgbẹ naa mejidinlogun lati Ward kẹsan-an, Ẹlẹrin, ni wọn fọwọ si iwe naa, ẹsun ṣeku-ṣẹyẹ ẹgbẹ oṣelu ni wọn si fi kan Alimi.

Wọn ni awọn ti fi ọrọ naa to gbogbo awọn agbaagba atawọn lameetọ ninu ẹgbẹ naa nijọba ibilẹ Irẹpọdun leti, igbesẹ to si tọna pẹlu agbekalẹ ofin ẹgbẹ lasiko yii ni lato kede idaduro ọkunrin naa.

Ṣugbọn ninu awijare tirẹ, Alimi ṣalaye pe ko si ẹnikẹni to pe oun lati beere ọrọ lẹnu oun lori ọrọ naa gẹgẹ bii alakalẹ ofin ẹgbẹ APC, o ni wọn ko fi ẹsun kankan kan oun, ati pe ori ẹrọ ayelujara loun ti n gbọ pe wọn da oun duro, oun yoo si gbe igbesẹ to tọ labẹ ofin.

A oo ranti pe nnkan ko fi bẹẹ dan mọnran laarin Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ati Gomina Oyetọla, bẹẹ ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC l’Ọṣun pin si meji labẹ awọn mejeeji. Nigba ti awọn Ileri Oluwa wa fun Oyetọla, awọn TOP sọ pe ibi ti Arẹgbẹṣọla ba n lọ lawọn n ba a lọ.

Ẹni to jẹ alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ, Alagba Biyi Adelọwọ, to si tun jẹ alaga TOP lọwọlọwọ ni wọn kọkọ kede idaduro rẹ loṣu to kọja, ko too di pe o kan Alimi bayii.

Leave a Reply