Ija ati awuyewuye to n waye laarin olorin fuji nla nni, Alaaji Wasiu Ayinde Marshal, ẹni ti gbogbo aye n pe ni K1The Ultimate, ati awọn ẹbi Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister, oludasilẹ ere Fuji, ti pari bayii o. Oloye Ebenezer Obey ti i ṣe oga awọn onijuju, to si jẹ igilẹyin ọgba pataki fun Barrister nigba aye rẹ lo pari ọrọ naa fun wọn nile rẹ.
Wasiu Ayinde funra rẹ lo gbe ọrọ naa jade lori oju-iwe fesibuuku rẹ lanaa yii, to ni, “Pẹlu ogo fun Ọlọrun, mo kede ipade ara-tunra-ri to waye laarin emi, Olasunkanmi Ayinde Marshall (Mayegun ilẹ Yoruba), gẹgẹ bii olori ẹbi, ati wọn ẹbi Oloogbe Dokita Ayinde Barrister. Ile Baba wa agba, Oloye Ebenezer Obey, to wa ni Ikẹja nipade atunṣe naa ti waye. Niṣoju Alaaji Adisa Osiẹfa, ọrẹ oloogbe Barrister, ni ipade naa ti waye. Aarẹ ati akọwe agba Egbẹ awọn Onifuji ni Naijiria naa wa nibẹ. Gbogbo awọn ọmọ ati iyawo pata lo wa, awọn ti ko le wa n woran wa, wọnsi n da si i, lori intanẹẹti bi ipade naati n lọ! Eyii ni pe ko si ede-aiyede kankan ninu ẹbi wa mọ o. Eyi naa si ni ibẹrẹ ayẹyẹ iranti ọdun kẹwaa ti SAB (Sikiru Ayinde Barrister) jade laye, eyi ti a o ṣe ni ọjo kẹrindinlogun oṣu Kejila yii.”
Bayii ni Alaaji Ayinde Barrister kọ ọ sori ẹrọ ayelujara, ti ọpọ awọn ololufẹ orin Fuji si n sọ pe ko si ohun to dara to eyi, bẹẹ ni wọn n ṣadura fun Oloye Ebenezer Obey fun atunṣe to ṣe.
Ṣe lati bii ọjọ meloo kan ni ija rẹpẹtẹ ti wa laarin awọn ẹbi ati ololufẹ Ologbe Barrister pẹlu Alaaji Wasiu Ayinde, nigba ti ọkunrin naa ti ṣe ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu awọn oniroyin, to ti sọ pe ki i se Sikiru Ayinde lo da ere Fuji silẹ. Ọrọ naa bi awọn eeyan ninu gan-an, wọn si n ri Wasiu Ayinde bi alaimoore. Wọn ni ki lo de ti ko sọ iru ọrọ bẹẹ nigba ti Barrister funra ẹ wa laye, to waa jẹ nigba to ku lo n fi ete oke lu tilẹ bẹẹ. Ati pẹlu, wọn ni ọrọ bẹe ko tọ si i nitori ọmọ-ọdọ Ayinde Barrister ni ki oun naa too di olorin Fuji.
Ọrọ yii kan awọn ẹbi o si kan ọrẹ gbogbo, ati ogumlọgọ awọn ololufẹ orin Fuji kaakiri agbaye. Lati igba naa, ko si ohun yoowu ti Ayinde Wasiu yoo ṣe, eebu buruku ni yoo gba lọdoọ awon ti wọn ba ti n fẹ ti Barrister, koda awọn mi-in a maa leri lati kọ lu u nibikibi ti wọn ba ti ri i. Ṣugbọn wẹrẹ ni ọrọ naa yanju bayii, awọn ti wọn si mọ bi ọrọ ti pari ko yee dupẹ lọwọ Alaaji Adisa Osiẹfa, ẹni to ṣe bi ipade naa ti waye lọdo Ebenezer Obey.
Ọjọ Kerindilogun oṣu Kejila ọdun 2010 ni Alaaji Dokita Sikiru Ayinde Balogun (Ayinde Barrister), ẹni ti wọn n pe ni Mista Fuji gan-an, jade laye ni ileewosan kan ni London, ṣugbọn titi di asiko yii, ọrọ Oludasile Fuji naa ko parẹ laarin awon ololufẹ orin Fuji gbogbo.