Ija kan n fẹju bọ nile Oloogbe Moshood Kaṣimawo Abiọla bayii o. Ija naa ti le debii pe apa awọn mọlẹbi ko ka a, ọrọ ti di ti kootu. Awọn ọmọ Abiọla meji, Kassim ati Aliyu, ti pe awọn ọlọpaa lẹjọ nitori orogun iya wọn, Alaaja Adebisi Abiọla. Bẹẹ a ki i ti kootu bọ ka tun ṣọrẹ, ohun ti yoo gbẹyin ọrọ yii, ẹni kan ko ti i le sọ.
Ohun to fa ija ni ọrọ awọn ole ti wọn waa fọ ile Abiọla nibẹrẹ oṣu yii, ti wọn si ko nnkan olowo iyebiye lọ. Lẹyin tawọn ole yii ti jale tan, awọn ọlọpaa pada wa sile Abiọla lalẹ pata ọjọ keji oṣu kẹsan-an yii ki kan naa, wọn si mu Kassim ati Aliyu lọ, wọn ni orogun iya awọn, Alaaja Adebisi, lo ni ki wọn mu awọn daadaa, pe o ṣee ṣe ki awọn mọ nipa ifọle naa. Ohun ti awọn ọmọ yii tori rẹ gba ile-ẹjọ lọ ree.
Lọọya nla Eko kan, Mike Ozekhome, lo ba wọn pe ẹjọ naa, ohun ti wọn si ro ninu iwe ipẹjọ wọn ni pe orogun iya awọn lo dẹ awọn ọlọpaa sawọn, to pe awọn ni adigunjale lori ẹsun ti awọn ko mọwọ, ti awọn ko mẹsẹ. Ninu iwe ipẹjọ wọn yii, wọn ni lọjọ ti awọn ọlọpaa wa mu awọn yii, niṣe ni wọn gbe awọn gidi-gannku, ti gbogbo ara adugbo si pe le awọn lori, ti wọn n foju ole wo awọn. Nitori ẹ ni wọn ṣe fẹẹ gba miliọnu lọna ọgọrun-un lọwọ awọn ọlọpaa, wọn ni mimu ti wọn mu awọn ko tọna rara.
Yatọ si pe wọn mu awọn bayii, wọn ni niṣe ni wọn fiya jẹ awọn ninu sẹẹli wọn, ti wọn ko si jẹ ki ẹnikẹni foju kan awọn, titi dori awọn lọọya awọn paapaa. Lọjoi keji, wọn tun ko wọn pada si ile Abiọla lati lọọ tu yara ti wọn n gbe wo yẹbẹyẹbẹ, ṣugbọn wọn ko ba kinni kan to le fi han pe wọn lọwọ si iwa bẹẹ, tabi pe wọn ni iwa kan to buru ti wọn n hu rara.
Ṣugbọn pẹlu ẹ naa, lati ọjọ yii ni wọn ti ti wọn mọle ti wọn ko si fi wọn silẹ, eyi to si buru ni pe awọn ọmọ naa n mura lati lọ si orilẹ-ede Amẹrika fun ẹkọ iwe wọn ni. Ozekhome sọ fun ile ẹjọ giga lEkoo pe ko paṣẹ fun awọn ọlọpaa ki wọn fi Kassim ati Aliyu silẹ, ki wọn si mura lati san ọgọrun-un kan miliọnu fun wọn.