Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Tiṣa lọkunrin tẹ ẹ n wo yii nileewe aladaani kan ti wọn forukọ bo laṣiiri nipinlẹ Ogun, Matthew Adebayọ lo n jẹ, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn (26) ni. Awọn ọlọpaa teṣan Ṣango, nipinlẹ Ogun, ti mu un bayii, wọn ni niṣe lo n ko ibasun tulaasi fun akẹkọọbinrin kan ti wọn forukọ bo laṣiiri, to ni iyẹn ko ni i yege idanwo Wayẹẹki to n ṣe bi ko ba gba koun maa ba a sun.
Matthew ti n ba ọmọbinrin ẹni ọdun mẹẹẹdogun naa lo pọ latigba ti wọn ti bẹrẹ imurasilẹ idanwo Wayẹẹki ninu oṣu kẹjọ. Ohun to sọ fọmọ naa ni pe oun gẹgẹ bii tiṣa ko ni i jẹ ko paasi bi ko ba gba koun maa ba a laṣepọ, n lo ba bẹrẹ si i mu ọmọ naa jade lọwọ alẹ lọ sinu kilaasi kan, nibẹ lo ti n fipa ba a sun, to si ni ko gbọdọ sọ fẹnikẹni.
Nigba ti ara ọmọbinrin naa ko gba ere ojoojumọ yii mọ lo sọrọ naa fun iya to ni ileewe naa, niyẹn ba lọọ sọ fun wọn ni teṣan ọlọpaa Sango, lọdọ DPO Godwin Idehai, ni wọn ba waa fọwọ ofin gbe Matthew, o si jẹwọ pe loootọ loun n ba akẹkọọ naa sun latigba ti eto idanwo naa ti bẹrẹ.
DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fiṣẹlẹ yii to ALAROYE leti ṣalaye pe ọga awọn, CP Edward Ajogun, ti ni ki wọn gbe tiṣa to ṣe aṣemaṣe naa lọ sẹka to n ri si ifiyajẹ awọn ọmọde, ki wọn wadii ẹ daadaa, ki wọn si gbe e lọ si kootu laipẹ.
Ni ti ọmọ to n ba lo pọ, ileewosan ni wọn gbe e lọ fun itọju to yẹ leyin ibasun rẹpẹtẹ to fara ko.