Ẹrọ idibo to le ni ẹgbẹrun marun-un lo bajẹ nibi ina to jo l’Ondo- INEC

Iyiade Oluṣẹyẹ, Akurẹ

Kọmiṣanna to wa fun eto iroyin ati ilanilọyẹ nipa idibo ti ajọ eleto idibo ilẹ wa, (INEC), Festus Okoye ti ṣalaye pe ẹrọ idibo ti wọn n pe ni card reader to le ni ẹgbẹrun-un marun-un (5100) lo jona gburugburu nibi ijamba ina to ṣẹlẹ nileeṣẹ ajọ naa niluu Akurẹ, nipinlẹ Ondo ni alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lori iṣẹlẹ naa lo ṣalaye pe ẹka ileeṣẹ naa to wa fun iroyin ati ibaraẹnisọrọ ni ina naa jo.

ALAROYE gbọ pe ko ti i sẹni to le fidi ohun to ṣokunfa ina to bẹrẹ ni nnkan bii aago mẹsan-an ku diẹ naa mulẹ. Ọpọlọpọ nnkan ni ina naa bajẹ ninu  ọọfiisi to wọ, ẹrọ idibo to le ni ẹgbẹrun marun-un lo si fara gba a.

Ọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ni eto idibo gomina yoo waye nipinlẹ Ondo.

Leave a Reply