Ijamba ina ṣẹlẹ laafin Ọọni, ọpọ dukia lo ṣofo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Akọwe iroyin fun Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọtunba Moses Ọlafare, ti sọ pe ẹnikẹni ko fara pa, bẹẹ ni nnkan iṣẹmbaye kankan ko ba iṣẹlẹ ina to ṣẹlẹ ninu aafin naa lọ.

Aago mọkanla aabọ alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni ina deede ṣẹ yọ ninu ọkan lara awọn ile to wa ninu aafin naa.

Ọlafare ṣalaye pe kia ni awọn oṣiṣẹ ajọ panapana ti dide, ti wọn si pa ina naa lati ma ṣe jẹ ko ran lọ sinu awọn ile miiran ninu aafin.

O ni awọn nnkan to n lo ina mọnamọna ninu ile ọhun lo kọ lu ara wọn, to si ṣokunfa ijamba naa, ṣugbọn ko si ẹmi kankan to ba iṣẹlẹ naa lọ.

 

Leave a Reply