Eeyan mẹrindinlogun jona ku ninu ijamba ọkọ l’Ọdẹ-Omu

Florence Babaṣọla, Osogbo

O kere tan, eeyan mẹrindinlogun lo jona kọja idanimọ, nigba ti awọn mọto meji fori sọra wọn niluu Ọdẹ-Omu, nipinlẹ Ọṣun, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin yii.

 

Olugbe ilu Ọdẹ-Omu kan to sun mọ ibi tisẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, Fatai Lasisi, ni ni nnkan bii aago mefa irọlẹ niṣẹlẹ naa waye. O ni bọosi Mazda elero mejidinlogun kan pẹlu mọto Lexus kan ni wọn fori sọ ara wọn.

Ọna Oṣogbo ni mọto boọsi naa ti n bọ, o si ko gaasi sinu buutu rẹ, nigba ti mọto Lexus naa n bọ latipinle Eko, to si n lọ siluu Oṣogbo.

Lasisi ṣalaye ṣe ni bọọsi naa dori kọ inu igbo nigba ti mọto Lexus naa gba a, loju-ẹse lo si gbina nitori afẹẹfẹ gaasi idana to ko sinu mọto ọhun.

Bakan naa, Ogbẹni Kareem Isau to je alaga ẹgbẹ awọn onimọto (NURTW),  tẹlẹ niluu Ọdẹ-Omu, ṣalaye pe eeyan mẹrindinlogun, ninu eyi ti awọn ọmọde marun-un wa ni wọn ko oku wọn jade ninu bọọsi naa.

O ni awọn arinrin-ajo mẹta; ọlọpaa kan, agunbanirọ kan ati ọmọbinrin kan pẹlu dẹrẹba bọọsi to n lọ siluu Ibadan naa ni ori ko yọ ninu ijamba ọhun.

Isau sọ siwaju pe ọmọbinrin ti ori ko yọ ọhun lo ṣalaye pe agbegbe ibudokọ Arẹgbẹ, niluu Oṣogbo, ni bọọsi naa ti gbera, bi awọn to n fun ọmọ lọyan ṣe wa ninu ẹ naa ni awọn miiran jokoo lẹsẹ ara wọn.

Alukoro fun ajọ ẹṣọ ojuupopo nipinlẹ Ọṣun, Agnes Ogungbemi, sọ pe awọn ko ti i mọ iye awọn to ku ninu ijamba naa, ṣugbọn wọn ti ko awọn to fara pa lọ sileewosan kan fun itọju

Leave a Reply