Wọn ti mu Hashimu, ọmọ ọdun mẹrin lo fipa ba lo pọ

Monisọla Saka

Ọwọ ileeṣẹ aabo ara ẹni laabo ilu, Nigeria Security and Civil Defence Corps (NCSDC), sifu difẹnsi, ẹka ipinlẹ Nassarawa, ti tẹ ọkunrin ẹni ọdun mejidinlogun (18) kan, Ibrahim Hashimu, fun bo ṣe fipa ba ọmọọdun mẹrin kan lajọṣepọ.

Agbẹnusọ ajọ naa, DSC Jerry Victor ṣalaye fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, pe afurasi ọhun huwa laabi yii lagbegbe Angwan Magaji, loju ọna aafin Ẹmia ni Lafia, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ naa lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

O ni niṣe ni wọn ri ọmọdebinrin naa to n sunkun pẹlu ẹjẹ balabala ni gbogbo ara ati aṣọ ẹ. Lẹyin ti mama ẹ tẹ ẹ ninu daadaa, to si fi i lọkan balẹ pe ko si kinni kan ti yoo ṣẹlẹ, lọmọ naa ṣalaye ohun ti oju rẹ ri lọdo ọkunrin agbaaya yii fun iya rẹ.

Victor fi kun un pe ni kete ti iroyin iṣẹlẹ naa de etiigbọ awọn lawọn ti gbe igbesẹ kiakia, eyi lo si ṣe atọna bọwọ awọn ṣe tẹ Ibrahim Hashimu, tawọn fi mu un wa si ileeṣẹ ajọ NCSDC, fun ifọrọwanilẹnuwo ati iwadii.

Wọn ni afurasi yii jẹwọ pe loootọ loun ṣẹ si ẹsun iwa ifipa ba ọmọ kekere lo pọ ti wọn fi kan oun, ṣugbọn ki wọn dakun, ki wọn ṣiju aanu wo oun.

O tẹsiwaju pe ni kete ti iwadii ba ti n pari lawọn yoo taari afurasi yii lọ siwaju adajọ.

Leave a Reply