Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
O kere tan, ọna mẹta ọtọọtọ ni ina ti ṣọṣẹ layaajọ ọdun Keresi niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, to si fi ọkẹ aimọye dukia ṣofo. Ọkan ṣẹlẹ lagbegbe Balogun Fulani, nibi ti ṣọọbu mẹrin ti jona raurau. Iṣẹlẹ ina keji ṣẹ ni Opopona Coca-Cola, nigba ti iṣẹlẹ ijamba ina kẹta waye lagbegbe Adewọle, niluu Ilọrin, bakan naa.
Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ajọ panapana ni Kwara, Hassan Hakeem Adekunle, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ lalẹ ọdun Keresi lo ti ṣalaye pe ṣe ni ajọ naa n gba ipe pajawiri leralera, ti ipe si n kọ lu ara wwọn, tawọn araalu n pariwo pe ina ti n ṣọṣẹ lawọn agbegbe wọn. O tẹsiwaju pe ipe akọkọ ni ajọ naa gba lati ile Alaaji Umar, nibi ti ina ti n jo ile oniyaara mẹwaa kan ti ṣọọbu mẹrin wa lara rẹ, ti ọpọ dukia si ba iṣẹlẹ naa lọ ki ajọ naa too ri ina ọhun pa, bakan naa ni wọn tun gba ipe miiran lati Agboole Okoosi, ladojukọ Otẹẹli Grace Lodge, l’Opopona Coca-Cola, niluu Ilọrin, ti ọpọ dukia tun ṣofo sọwọ ina.
Adekunle ni iṣẹlẹ jamba ina kan tun waye lọjọ Keresi yii kan naa ni ile Abọlarinwa, to wa lẹyin Otẹẹli Henry George, lagbegbe Adewọle, ti ajọ panapana si lọọ pa ina naa ko too ba nnkan jẹ jinna, bo tilẹ jẹ pe ọpọ dukia lo ti ṣofo nibi ijamba ina naa. O ni oun tawọn gbọ ni pe ina ẹlẹntiriiki lo ṣokunfa awọn ijamba ina mẹtẹẹta to waye naa.
Ọga ajọ panapana ni Kwara, the Director, Kwara, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, rọ gbogbo olugbe ipinlẹ naa lati maa ṣọra fun gbogbo awọn nnkan to le ṣokunfa ijamba ina lawọn inu ile ati ọfiisi gbogbo lati dẹkun pipadanu dukia sọwọ ina.