Ijamba ina fọkẹ aimọye dukia ṣofo n’Ilọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Titi digba ti a n ko iroyin yii jọ, ko sẹni to mọ ohun to ṣokunfa ijamba ina kan to n dun kẹu kẹu, to si fi ọpọ dukia ṣofo lagbegbe Ìta-Àmádù, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lasiko ayẹyẹ ọdun Ajinde.

Gbogbo igbiyanju awọn araadugbo lati pana ọhun lo ja si pabo, ti ina yii si ti ba nnkan jẹ jinna ko too di pe awọn oṣiṣẹ panapana de, ṣugbọn gbogbo akitiyan wọn lati pana naa lo ja si pabo, ṣe ni ina ọhun fẹju kẹkẹ.

Ọkunrin kan to n gbe lagbegbe naa, ṣugbọn ti ko darukọ rẹ fun wa ṣalaye pe ni nnkan bii aago mejila oru ni ijamba ina ti ko sẹni to mọ ohun to ṣokunfa rẹ yii waye, ti agbara awọn araadugbo ko si ka a. O tẹsiwaju pe ninu sọọbu kan ni ina ọhun ti sẹ yọ to si ran mọ ile.

O ni bi ina ṣe bẹrẹ nibẹ lo n ran mọ gbogbo nnkan to wa layiika, ko si pẹ rara to fi ran mọ awọn ile to wa lẹgbẹẹ rẹ.

O fi kun un pe gbogbo awọn ti wọn n gbe awọn ile naa ni wọn n fọn sita lai mu ohunkohun, bi awọn kan ṣe n bu omi, lawọn kan n pe ileeṣẹ panapana, ti ero si se patimu nibi iṣẹlẹ naa.

Ṣugbọn ijọloju lo jẹ pe bi wọn ṣe n pa ina naa to lo tun n pọ si i, ṣe ni eefin n ru lati origun kan si ekeji, titi ti ileeṣẹ panapana fi de, ṣugbọn nnkan ti bajẹ jinna, ọpọ dukia ti segbe.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ileeṣẹ panapana nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Hakeem Adekunle, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni wọn ko tete kan si ileeṣẹ panapana lo fa a ti agbara ko fi tete ka ina naa.

Bo tilẹ jẹ pe ko si ẹni ti ẹmi rẹ ba iṣẹlẹ naa lọ, sibẹ ọkẹ aimọye miliọnu Naira ni dukia to ṣofo nibẹ.

Leave a Reply