Ijamba ina nla ṣẹlẹ l’Ekoo, wọn ni ọkọ agbepo lo ṣubu lojiji

Bo o lọ o yago lọrọ da lowurọ kutu oni, Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nigba ti tirela ọkọ agbepo ṣubu lojiji, to si gbina lagbegbe Toyota, lẹgbẹẹ Mile 2, lojuna marosẹ Oshodi si Apapa, l’Ekoo.

Ojuna mejeeji ni ina buruku yii gba, eyi to ṣoro fun awọn awakọ lati gba ̀ọna to lọ si Mile 2 tabi awọn to n pada si Oṣodi, niluu Eko.

Loju-ẹsẹ ti iṣẹlẹ yii waye la gbọ pe awọn ẹṣọ to n ri si awọn iṣẹlẹ pajawiri ti de sibẹ lati pana ọhun, bẹẹ ni ko ti i si aridaju kan pe iṣelẹ yii gba ẹmi ẹnikẹni.

 

Leave a Reply